Kí ló dé tí Naíjíríà yarí láti gba ọ̀pọ̀ àtìpó ọmọ ilẹ̀ Venezuela tí Trump fẹ́ fi ránṣẹ́?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Minisita to n risi ọrọ nipa oke okun lorilẹede Naijiria, Yusuf Tuggar ti jẹ ko di mimọ pe orilẹede Naijiria ko ni juwọ silẹ si igunkoko lati ọrilẹede Amẹrika lati tẹwọ gba awọn eeyan Venezuela ti wọn fẹ wa ṣe atipo ni Naijiria ati idunkoko lori ọrọ fisa ati afikun owo itaja.

Yusuf Tuggar sọ fun ileeṣẹ iroyin aladani Channels TV pe orilẹede Naijiria gan ni ọpọ iṣoro lati dojukọ ni ikapa rẹ, ti ko si le jẹ orilẹede kẹta fun awọn ẹlẹwọn lati oke okun ti ijọba Trump fẹ ko wa silẹ adulawọ.

"Ni bayii, a ni eeyan to le ni milọnu 230. Ẹyin naa ni ẹ ma bu wa ti a ba gba awọn ẹlẹwọn Venzuela yii wọle si Naijiria," minisita ṣalaye.

"Ko tọna fun orilẹede Naijiria lati gba ọọdurun ẹlẹwọn Venezuela wọle ," o sọ , to si tun mẹnu ba ofin ti Amẹrika gbe kalẹ lati dena de awọn arin irinajo.

Bakan naa ni, Aarẹ Donald Trump tun dunkoko mọ awọn orilẹede ti wọn n ṣe ẹgbẹ Brics ti wọn tako Amẹrika pẹlu afikun owo itaga ida mẹwaa,

Orilẹede Naijiria ko ti ọmọ ẹgbẹ Brics pẹlu gbogbo ara ṣugbọn o di orilẹede kẹsan an to n sisẹ pẹlu ẹgbẹ naa ninu oṣu Kini.

Tuggar ni dunkoko afikun yii ni ko ni ṣe pẹlu didarapọ mọ ẹgbẹ Brics.

"Ẹni lọkan pe Amẹrika n dunkoko mọ awọn orilẹede Afrika kan pe ki wọn tẹwọgba awọb atipo Venezuela, to jẹ pe awọn kan ninu ṣẹsẹ kuro ni ọgba ẹwọn ni.

"O nira pupọ fun orilẹede bi Naijiria lati ṣe eyi. A ni iṣoro ti wa , a ko le tẹwọgba awọn eeyan yii ni tori Ọlọrun."

Ọrọ Tuggar yii lo jẹyọ lẹyin ipade to waye laarin aarẹ Trump ati awọn ilẹ Afrika Marun un, Liberia, Senegal, Mauritania, Gabon ati Guinea-Bissau pe ki wọn tẹwọ gba awọn eeyan yii ti US fẹ le kuro, to jẹ orilẹede abibibi wọn gan ti kọ wọn.

Ẹwẹ, minister fun ọrọ oke okun ni Liberia ti ni oun ko tẹwọgba irufẹ iroyin bẹẹ lati orilẹede Amẹrika.

Ki lo sẹlẹ saaju?

Saaju ni ijọba orilẹe ede Amẹrika kede atunṣe si bi awọn eeyan lati orilẹ ede mii ṣe le ṣabẹwo si orilẹ ede naa to fi mọ orílẹ ede Naijiria.

Atunṣe sI eto gbigba "físà" si orilẹ ede Amẹrika yii ti wọn pe ni 'Visa Reciprocity Policy for Nigeria' yoo bẹrẹ loju ẹsẹ.

Igbesẹ tuntun yii maa ni ipa lori awọn to ba ṣe abẹwo si Amẹrika amọ ko ni ni ipa lori awọn to ba fẹ gba fisa lati maa lọ gbe ni Amẹrika.

Eyi tumọ si pe lati asìko yii, ọmọ Naijiria to ba fẹ gba fisa lati lọ ṣabẹwo si Amẹrika ko ni ni anfani lati wọ orilẹ ede naa ju ẹẹkan pere lọ ati pe wọn ko ni ni anfani lati lo ju oṣù mẹta lọ