You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ikú ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí alárùn HIV/AIDS bíi 400m, èèyàn 6m tuntun le kó àrùn náà torí ìrànwọ́ Amẹ́ríkà tó dúró
- Author, Mayeni Jones
- Role, BBC News, Johannesburg
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Ọkan lara awọn ti wọn maa n gba oogun itọju kokoro arun HIV lati ọdọ ajọ oluranlọwọ USAID ni obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Gugu, ileewosan kan lo ti maa n gba a ni Johannesburg, lorilẹede South Africa.
Ṣugbọn nigba ti Aarẹ Dobald Trump ti yọwọ iranwọ naa nibẹrẹ ọdun yii, Gugu ati ọpọ eeyan to n gbele aye pẹlu HIV ti bọ sinu iṣoro ọjọ iwaju ti ẹsẹ rẹ n mi nilẹ ni South Africa.
Ohun kan ti Gugu n dupẹ fun, ko ju pe ileewosan to ti n gba oogun naa pe e, ki wọn to ṣiwọ iṣẹ, wọn ni ko waa gba oogun ti yoo ro o lagbara naa, kawọn to ko igba wọle bi aṣẹ ijọba America.
"Mo wa lara awọn ti wọn ri aanu gba nipa lilọ gba oogun naa lọpọ.
Mo maa n gba eyi ti mo maa lo fun oṣu mẹta silẹ ni.
Ṣugbọn ki ileewosan mi to tilẹkun wọn pa, wọn fun mi ni oogun ti maa lo fun oṣu mẹsan-an silẹ"
Nigba ti yoo ba fi di oṣu Kẹsan-an ọdun yii ṣaa, oogun naa ti i ṣe ARV yoo tan, Gugu loun yoo lọ sileewosan apapọ lati gba si i.
Òwò nàbì ni Gugu n ṣe tẹlẹ, o ti fiṣẹ naa silẹ tan, ko to mọ pe oun ti lugbadi arun HIV, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta (54) ni bayii.
Ọdun mẹwaa sẹyin ni ikọ kan kọlu Gugu, o loun tiẹ ro pe ikọ ife ti a mọ si Tuberculosis ni.
O tọ dokita kan lọ, iyẹn si sọ fun un pe kokoro aya lo n da a laamu, o si tọju rẹ nigba naa.
"Ṣugbọn nigba ti itọju yẹn ko kaju ohun to n ṣe mi, mo lọ ṣayẹwo arun ko gboogun (HIV). Mo ti n ro o funra mi pe mo ti ni HIV, mo si sọ bẹẹ fun nọọsi to yẹ mi wo."
Abajade ayẹwo naa ni pe o ti ni HIV, latigba naa ni Gugu, ti a fi ojulowo orukọ rẹ bo laṣiri, si ti n lo oogun ARV lati gbe ara rẹ ro.
Ileeṣẹ kan ti ki i ṣe tijọba lo n ba ṣiṣẹ bayii bii alabojuto.
"Awa la maa n ran awọn aṣẹwo to ba loyun lọwọ lati ri i pe ọmọ ti wọn maa bi ko ni arun HIV, a maa n ba wọn gba oogun ARV.
A tun maa n bẹ wọn wo nile lati ri i daju pe wọn n lo oogun wọn deede, a si maa n ba wọn wo ọmọ wọn bi wọn ba lọ fun ayẹwo oloṣooṣu wọn."
Ọpọ oninabi ni South Africa ni wọn maa n lo ileewosan adani ti America n ṣe iranwọ owo fun lati gba oogun HIV, ajọ USAID ti ko si mọ bayii lo n ṣakoso rẹ nigba yẹn.
Ṣugbọn pupọ wọn lo ti wa ni titipa bayii nigba ti Trump ti ge owo iranwọ ku nibẹrẹ ọdun yii.
Atẹjade kan ti wọn fi lede l'Ọjọbọ lati ọdọ ajọ UN, sọ pe adinku iranwọ naa ti ko ọpọ eeyan laya soke kaakiri agbaye.
" Irufẹ kokoro HIV tuntun ti ko ba jẹ jade, dinku ni ida ogoji (40% ) lati 2010, ọpọ ọmọde to to 4.4 million si ni wọn ri aabo lọwọ arun naa lati ọdun 2000.
O le ni miliọnu mẹrindinlọgbọn (26 million) ẹmi ti oogun ti wọn n ri gba naa da aabo bo ẹmi wọn."
Ajọ UNAIDS to ṣalaye yii, kilọ pe bi gbogbo agbaye ko ba tete gbe igbesẹ, kokoro HIV tuntun to to milionu mẹfa le jẹyọ, miliọnu mẹrin eeyan si le padanu ẹmi lati ara HIV nigba ti yoo ba fi di 2029.
Báwo ni ìrànwọ́ tó dópin yìí ṣe bẹ̀rẹ̀?
Aarẹ America nigba kan, George W Bush, fi eto nla kan lọlẹ lati gbogun ti HIV/Aids lọdun 2003, ohun to sọ nigba naa ni pe igbesẹ naa daa fun America pẹlu.
Eto to gbe kalẹ naa ni a mọ si 'President's Emergency Plan for Aids Relief (Pepfar), eto naa lo jẹ ki wọn ko owo to le ni $100bn (£74bn) si itọju arun HIV/Aids kaakiri agbaye.
Ni South Africa, eeyan to to 7.7 million lo n gbele aye pẹlu arun HIV, eyi lo si pọ ju lagbaaye, gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ UNAIDS.
O din diẹ ni miliọnu mẹfa (5.9 million)ninu awọn eeyan naa lo n gba itọju pẹlu oogun ARV, eyi si jẹ ki adinku de ba aisan naa ni ida 66%. Iku AIDS paapaa dinku lati 2010, bi UN ṣe sọ.
Ijọba South Africa gan-an fidi ẹ mulẹ, pe iranlọwọ Pepfar jẹ kawọn ri owo ṣe awọn eto miran, titi kan dida ileewosan alagbeka silẹ, kawọn eeyan le maa ri iwosan gba nirọrun.
Ṣugbọn nigba ti ijọba Donald Trump ti rẹ́ iranlọwọ naa bii ẹni to n rẹ ẹran, nnkan ko ri bii ti atijọ mọ.
" Bi ero temi, a maa bẹrẹ si i ri alekun ninu onka awọn to ni HIV bayii, bẹẹ naa lo maa ri fun awọn onikọ ife ati awọn arun mi-in to le ran ẹlọmiran."
Ọjọgbọn Lynn Morris, Igbakeji ọga agba ni Johannesburg's Wits University, lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
"A si maa bẹrẹ si i ri idakeji idunnu ti a ti n ri tẹlẹ, ipa wa ti n pin."
Bi oogun ARV yii ṣe pataki to, Gugu ṣalaye pe itọju rẹ wa laaarin iye ati iku ni, paapaa awọn eeyan to yan iṣẹ aṣẹwo laayo.
"Awọn eeyan ko fẹẹ ṣe alai lo oogun ARV wọn, ẹru ti n ba wọn bayii, pe ṣe awọn o ni i ku nigba tawọn ko ba ri i lo."
Bakan naa ni iranlọwọ to duro yii ti ṣakoba fun iṣẹ iwadii lati ri itọju fun HIV ati AIDS.
" A ko ni i maa ri abẹrẹ ajẹsara tuntun gba lati ṣayẹwo ati iwadii, bi kokoro HIV tuntun gan-an ba yọju, a ko le ni iru anfaani iwadii ta a ni tẹlẹ lorii rẹ."
Ọjọgbọn Morris lo ṣe afikun bẹẹ.
Orilẹede South Africa jẹ ọkan lara awọn ilu ti wọn ti n ṣewadii nipa HIV ju lagbaaye. Ọpọ oogun to si n gbogun ti HIV lagbaaye lo n ti ibẹ wa.
Iru awọn oogun bẹẹ ni Prep (pre-exposure prophylaxis), oogun kan ti ki i jẹ ki ẹni ti ko ba ni kokoro HIV lugbadi ẹ.
Bakan naa ni wọn ṣe omiran to n dena HIV lọdun yii, wọn pe e ni Lenacapavir. Abẹrẹ ni, eeyan yoo gba a lẹẹmeji lọdun, o si maa n dena arun HIV delẹdelẹ ni. Orilẹede South Africa naa ni wọn ti gbiyanju rẹ.
Àwọn kan ṣi n bá ìwádìí lọ nípa HIV
Ninu yara iwadii ati ayẹwo ni Wits University', awọn onimọ ijinlẹ kan kora wọn jọ, wọn si n ṣiṣẹ iwadii lori HIV.
Awọn wọnyi ni amọye agba ti wọn wadii naa kaakiri orilẹede Africa mẹjọ, wọn n ṣe bẹẹ lati ri oogun ti yoo maa gbọ HIV patapata.
"A n ṣeto ajẹsara kan lati mọ bo ṣe n ṣiṣẹ si, a maa pada dan an wo lara eeyan." Ọjọgbọ Abdullah Ely lati Wits University lo sọ bẹẹ fun BBC ninu yara ayẹwo rẹ.
"Ero ọkan wa ni lati dan an wo ni awọn ilẹ Africa, nitori a fẹ ki iwadii yii ran awọn eeyan wa lọwọ pẹlu awọn eeyan agbaye yoku.."
Ṣugbọn owo ti America kasẹ rẹ nilẹ yii ti ṣakoba fun erongba wọn.
"Nigba ti aṣẹ de pa ka dawọ duro, o tumọ si pe a gbọdọ dawọ ohun gbogbo duro ni . Awọn diẹ ninu wa lo ri owo nibomi-in, o fa wa sẹyin gan-an fun ọpọ oṣu, o si le di ọdun paapaa"
Ọjọgbọn Ely lo ṣalaye bẹẹ.
"Òfò nla leyi fun South Africa. Ohun to tumọ si ni pe bi a ba tiẹ mu abọ iwadii kan jade ni Africa, Europe ni wọn yoo ti lọọ ṣayẹwo ẹ, tabi US."
Bẹẹ ni Ọjọgbọn Ely
Àwọn olùwádìí nílò 4.6bn, ìlérí 600m ni wọ́n rí
Loṣu Kẹfa, yunifasiti beere owo iranwọ ti iye rẹ jẹ 4.6bn lọwọ ijọba South Africa, iyẹn ($260m; £190m). Wọn beere owo naa lati fi di gbese to le kapa iṣẹ wọn fun ọdun mẹta, latari adanu to ba wọn lati ọdọ ijọba America.
"A n bẹbẹ fun iranwọ, nitori South Africa lo n lewaju ninu iṣẹ iwadii lori HIV, ṣugbọn ko ṣee da ṣe." Ọmọwe Phethiwe Matutu, ọga agba awọn ileewe fasiti ni South Africa lo sọ bẹẹ.
L'Ọjọruu, Minisita eto ilera ni South Africa, Aaron Motsoaledi, kede pe awọn ti ri ọna abayọ kan nipa owo ti awọn nilo.
O ni ajọ alaanu The Bill and Melinda Gates Foundation ati Wellcome Trust, ti gba lati fi miliọnu kan rand ti i ṣe owo South Africa silẹ(Ẹni kọọkan wọn). Wọn ni awọn yoo fi owo naa silẹ laipẹ rara, nigba ti ijọba yoo fi 400m silẹ fun ọdun mẹta to n bọ. Motsoaledi lo ṣalaye bẹẹ.
Apapọ owo naa yoo jẹ 600m rand, eyi to kere jọjọ si 4.6bn rand ti awọn oniṣẹ iwadii naa n beere lati ṣiṣẹ wọn.
Ni ti Gugu, ero rẹ ni pe nigba toun yoo ba fi di arugbo, wọn yoo ti ri oogun fun HIVAIDS. Ṣugbọn lọwọ yii, ireti rẹ ko to nnkan rara.
"Mo ni ọmọkunrin ọmọ ọdun mẹsan-an kan ti mo n tọju, o wu mi ki n pẹ laye, ki n duro tọ ọ titi digba ti mo ba le tọ ọ da."
Gugu lo sọ bẹẹ fun BBC.
"Ohun to wa nilẹ yii ki i ṣe iṣoro asiko yii nikan, a gbọdọ ronu nipa bi yoo ṣe nipa lori awọn iran awọn obinrin to n bọ ati awọn ọdọ."