Agbébọn ṣekúpa èèyàn márùn-ún àti oͅmoͅdé nínú ilé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Agbebọn kan ẹni ọdun mejidinlogoji ti gba ẹmi awọn ara adugbo rẹ,eeyan marun-un nilu ile wọn lagbegbe san Jacinto, ariwa Huston, lorilẹede Amẹrika.
Iṣẹlẹ ọhun lo sẹ nigba ti ariyanjiyan kan waye laarin ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji oun ati awọn amuleti rẹ, lori bi o ti n yinbon ti ariwo ibon rẹ ko jẹ ki awọn ọmọde sun.
Ninu awọn ti agbebọn oun pa ni obinrin meji kan,ọmọ ọdun mẹjo kan ti gbogbo wọn wa lati Orilẹede Honduras.
Awọn agbofinro cleveland ni,afurasi naa lo jẹ ọmọ orilẹede Mexico ti orukọ rẹ si jẹ Francisco Oropez,to si ti fi papa nara lẹyin ti isẹlẹ naa waye.
Capers giwa ile isẹ ọlọpaa agbegbe ọhun ni, Aja ati baalu to ni ẹrọ ayaworan ni wọn n fi wa afurasi naa,ti wọn si ni igbagbo wi pe o ṣeṣe ko sa pamo sinu igbo to wa ni agbegbe ọhun.
Eeyan mẹwa lo wa ninu ile naa ti afurasi agbebọn si fẹmi awọn marun sofo pẹlu ọmọ ọdun mẹjọ kan.
Veronica Pineda ni ọpọ igba ni iro ibọn ma n dun ni agbegbe awọn, ti ijọba si kọ lati sẹ isẹ lori rẹ,sugbọn iṣẹlẹ isẹkupani yii ya oun lẹnu.











