You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí lò fàá tí obìnrin kan fi dáná sun ara rẹ̀ ní Jigawa?
Kayeefi nla gbaa niṣẹlẹ ọhun jẹ fun ara abule Garin Mallam to wa nijọba ibilẹ Guri, ipinlẹ Jigawa nigba ti wọn gbọ pe iyaale ile, ẹni ogoji ọdun kan dana sun ara rẹ.
Obinrin naa da bẹntirolu si gbogbo ara rẹ ko to di pe o ṣa iṣana sira rẹ ninu igbo kan to sunmọ abule naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati ṣawari ohun to ṣẹlẹ gan-an ni pato.
Ṣugbọn sibẹ, ileeṣẹ ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe iwadii rampẹ ti awọn ṣe jẹ ko ye wọn obinrin naa ṣe ipinnu yii nitori awọn iṣoro to n dojukọ lẹyin iku rẹ lawọn oṣu diẹ sẹyin.
Gẹgẹ bi a sẹ gbọ, obinrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Fatsuma Bagobiri lọ sinu igbo funra rẹ lati ma jẹ ki awọn eeyan da oun lọwọ kọ lori igbesẹ to ti ṣe ipinnu le lori.
‘O n la ipenija iporuru ọkan kọja’
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa, DSP Lawan Shiisu Adam, sọ fun BBC pe iwadii rampẹ ti awọn ṣe fi han pe obinrin naa n la awọn ipenija to n ko iporuru ọkan ba a kọja, latigba ti ọkọ rẹ ti ku loṣu meloo kan sẹyin.
“Nigba to ṣegbeyo, to si jẹ tun yapa pẹlu ọkọ rẹ, iṣẹlẹ to ko oriṣiri wahala ati idaamu ba a, debi to fi bẹrẹ sii ro arokan lori iṣẹlẹ naa,” o ṣalaye.
O fi kun ọrọ rẹ pe obinrin naa ti gbe igbesẹ yii lati dana sun ara rẹ nigba kan, ṣugbọn to ja si pabo fun un.
Ọlọpaa naa tun sọ pe awọn gbọ nipa wi pe awọn to n gbe ninu ile oloogbe naa ni ipenija aniyan ọkan to n da wọn laamu.
“A gbọ pe pupọ awọn eeyan ninu mọlẹbi wọn ni wọn ni oriṣiriṣi aniyan to n da wọn laamu,” o jẹ ko di mimọ.
Ṣugbọn DSP Shiisu tẹsiwaju pe awọn ohun ti awọn n gbọ ni pe ohun ti obinrin yii n la kọja yii, ko ṣai ṣẹyin iyapa to ṣẹlẹ laarin oun ati ọkọ rẹ.
O tun jẹ ko di mimọ pe awọn yoo ranṣẹ pe ọkọ rẹ tẹlẹ ati awọn mọlẹbi rẹ lati wa fun wọn ni ẹri kikun nipa ohun ti wọn mọ.
Iku igbeyawo jẹ ohun to wọpọ lawọn agbegbe ariwa ilẹ Naijiria.
Ati pe lawọn igba miran, iṣẹlẹ naa maa n ṣoro lati gba fun awọn obinrin, pẹlu bo ṣe jẹ pupọ awọn obinrin ni wọn gbẹkẹ le awọn ọkọ wọn fun ounjẹ ati awọn nnkan miran ti wọn nilo ninu igbesi aye wọn.
Fun idi eyi, kikuro nile ọkọ tunmọ si pe iru obinrin bẹẹ yoo pada awọn anfaani yii, to si maa n ko wọn sinu iṣoro lọpọ igba, paapaa julọ bi wọn ko ba ri iranlọwọ lati inu mọlẹbi wọn ti wọn pada si.
‘Ẹya ara naa jona gidi’
DSP Lawan Shiisu sọ pe awọn ọlọpaa ṣawari oku naa ninu igbo, nibi to jona si.
“O lo bẹntiroolu to lọ ra, o daa si ara rẹ, o si ṣa ina, ko to di pe o fi si ara rẹ lara, to si jona patapata,” o ṣalaye.
Iroyin nipa ki eeyan gbẹmi ara rẹ lori awọn ipenija to n la kọja kii ṣe nnkan tuntun, ṣugbọn iru iṣẹlẹ bayii ni ko saba wọpọ lawujọ.
Ki lo n fa iporuru ọkan to le gidi?
Dokita Dayyaba Shaibu, to jẹ amkọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo nipa ilera to nii ‘se pẹlu ọpọlọ (mental health) niluu Abuja, sọ pe ko sẹni ti ko le ni iporuru ọkan, ati pe bo ṣe n wa lara awọn agbalagba naa lo n wa lara awọn ọmọde.
Ati pe, o ni o fẹẹ wọpọ laarin awọn obinrin ati awọn ọdọ ti wọn ti wa lọjọ ori to ti balaga.
Akọṣẹmọṣẹ oniṣegun nipa ilera ọpọlọ naa sọ pe nigba ti eniyan ba ni iriri ijamba, o maa n wa ninu ipo iporuru ọkan, bii ko padanu ẹni to sunmọ ọn, tabi ki wọn lee danu lẹnu iṣẹ, tabi ko bimọ ti yoo maa da agọ ara rẹ laamu, ati bẹẹbẹẹlọ.
Dokita Dayyibah sọ pe ẹya ara eeyan maa n ṣiṣẹ pataki nipa ninu iru awọn iṣoro bawọnyi.
“Awọn kan ni Ọlọrun ti da lati ni ifarada. Koda, bi ohun to burujai ba ṣẹlẹ si wọn, o maa gbọnra jigi lati ma ṣe jẹ ko duro ninu ọkan rẹ.
“Awọn kan ko ri bẹẹ. Ọlọrun da wọn pẹlu irẹwẹsi lati ma ṣe le la adojukọ kọja. Awọn si ni wọn maa n la oniruuru ipenija iporuru ọkan to le kọja,” gẹgẹ bi dokita naa ṣe ṣalaye.
Ṣugbọn o sọ pe nigba miran, eniyan maa n ronu kọja aaye ti yoo fi wa fa aarun sii lara.