You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n pa akẹ́kọ̀ọ́ Kwara Poly ṣe lọ nílé ẹjọ́
Ni ọjọ kẹrinla osu kẹwa ọdun yii ni ajọ ọlọpaa ipinlẹ naa kede wi pe wọn ti gbasọ lọrun awọn ọlọpaa mẹta yii lẹyin ti wọn pari iwadii wọn lori iṣẹlẹ naa
Ile ẹjọ Majisireeti kan ni iluu Ilorin ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ igbẹjọ lori awọn ọlọpaa mẹta ti wọn fura si pe wọn pa akẹkọọ ile ẹkọ gbogbonise Kwara Poly, Abdulyekeen Abdulquyum.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni, igbimọpọ ọdaran ati ipaniyan ti o lodi si ofin orile-ede Naijiria.
Tẹ o ba gbagbe ni ọjọ kẹrin osu kẹsan-an ọdun yi ni a gbọ pe akẹkọọ naa ku si ile iwosan lẹyin ti wọn ni awọn ọlọpaa le e, ti wọn si yinbọn fun-un.
Orukọ awọn ọlọpaa yii ni; Kayode Abiodun ti ọjọ ori rẹ jẹ ọdun mẹtadinlaadọta, James Emmanuel, ẹni ọdun mejilelogoji ati Oni Philip, ẹni ọdun marundinlogoji.
Ni ọjọ kẹrinla osu kẹwa ọdun yii ni ajọ ọlọpaa ipinlẹ naa kede wi pe wọn ti gbasọ lọrun awọn ọlọpaa mẹta yii lẹyin ti wọn pari iwadii wọn lori iṣẹlẹ naa.
Iwaju Magistrate Felicia Sha'aba ni wọn wọ wọn wa, ti wọn si n lami loju.
Àlàyé lórí bí ìgbéjó ṣe lọ
Ni ibẹrẹ igbẹjọ, ile ẹjọ ka iwe ipẹjọ ọlọpaa si awọn afurasi naa leti,
Iwe ipẹjọ naa ka bayi pe, ni ọjọ kẹrin osu kẹsan-an ọdun 2024 ni arakunrin kan, Abdulrahman Ero-Alujana ti Alagbon, Oke Adini Ilorin gba ipe lati ọdọ arakunrin kan, Yakubu pe, wọn ba ọmọ ọmọ rẹ ninu agbara ẹjẹ ni agbegbe ile epo Kayowa.
Iwe ipẹjọ naa jẹ ka mọ pe, nigba ti ọkunrin naa debẹ, o ba ọmọ ọmọ rẹ, Abdulyekeen Abdulquyum, to ti doloogbe bayii ninu agbara ẹjẹ, ọmọ naa si sọ fun-un pe awọn ọlọpaa lo ṣe akọlu si oun.
"O sare gbe e digba-digba lọ ile iwosan ikọsẹ fasiti Ilorin nibi ti o ti n gba itọju ki dokita to kede pe o ti ku.
"Iwadii fi han pe, Kayode Abiodun, James Emmanuel ati Oni Philip lọwọ ninu iṣẹlẹ to seku pa Abdulyekeen Abdulquyum.
"Iwadii fini-fini tun sọ ọ di mimọ pe awọn afurasi mẹta yii ti wọn jẹ ọlọpaa tẹlẹ ri ki wọn to gbasọ lọrun wọn fi ibi isẹ wọn to jẹ agbegbe Fate silẹ, lọ si iwaju ile ẹkọ Champion, nibi ti wọn ti da Abdulyekeen Abdulquyum duro, ti wọn si le e, wọn tun gun-un lọwọ, wọn si fii kalẹ sinu agbara ẹjẹ.
"Ninu iwadii, iwọ Oni Philip sọ pe o le Abdulyekeen Abdulquyum lọ labẹ idari Kayode Abiodun, o si fiilẹ sinu agbara ẹjẹ lati wa sọ fun Kayode Abiodun ati James Emmanuel.
"Iwadii fihan gbangba pe Kayode Abiodun, James Emmanuel ati Oni Philip gbimọpọ lati fa iku Abdulyekeen Abdulquyum nigba ti ẹ le e, gun-un ni nkan, ẹ si fii sinu agbara ẹjẹ"
Lẹyin eyi ni agbẹjọro wọn, Adekunle Iwalaye rọ ile ẹjọ fun beeli ati oniduro fun awọn onibara rẹ.
Agbefọba Olajide Emmanuel ta ko o, o si gbe iwe ọdaran aile gba beeli (Motion Exparte) ti wọn lẹ mọ iwe ipẹjọ wọn sita fun ile ẹjọ.
Ìdájọ́ adájọ́
Lẹyin atotonu awọn mejeji, adajọ Felicia Sha'ba pasẹ ahamọ fun wọn ni ile atunse Oke-Kura ni Ilorin, lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ mii.