Àwọn agbébọn tún ya wọ ilé ẹ̀kọ́ míì, jí akẹ́kọ̀ọ́ 15 gbé lọ ní Sokoto

Awọn agbebọn tun ti ikọlu agbegbe Gidan Bakuso, nijọba ibilẹ Gada nipinlẹ Sokoto ni apa ariwa orilẹede Naijiria, ti wọn si ji akẹkọọ mẹdogun mii gbe lọ.

Ọmọ ile igbimọ aṣojusofin to n soju agbegbe naa, Bashir Usman Gorou lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC.

O ni akẹkọọ mẹdogun ati obinrin mẹrin ni awọn agbebọn naa ji gbe lọ.

O tẹsiwaju pe awọn agbebọn yii ṣekọlu si agbegbe naa ni oru ọgajọ lọjọ Ẹti lasiko ti awọn araalu n sun lọwọ.

Gorou ni awọn akẹkọọ lo jẹ akẹkọọ ile ẹkọ Allo, ti ọjọ ori wọn si bẹrẹ lati ọmọ ọdun mẹjọ si ọmọ ọdun mẹdogun.

“Lẹyin awọn akẹkọọ to wa ni akata ni awọn ajinigbe yii, o le ni araalu mẹtalelọgọta to wa ni ahamọ awọn ajinigbe sugbọn igba kọkọ ti wọn yoo wa ji awọn akẹkọọ gbe ree.”

Agbẹnusọ fun Ileeṣẹ ọlọpaa, ASP Ahmad Rufai sọ fun BBc ileeṣẹ ọlọpaa ko ti gbọ nnkan nipa isẹlẹ naa sugbọn wọn ti gbera lati fidi isẹlẹ naa mulẹ.

O ni oun yoo kesi wa pada kete ti wọn ba ti pari iwadii lori iṣẹlẹ ijinigbe naa.

Bẹẹ ba gba gbe, Akẹkọọ to le ni 280 lawọn agbebọn kan ji gbe niluu Kuriga, agbegbe Chikun, to wa ni ipinlẹ Kaduna.

Isẹlẹ yii lo waye lowurọ Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2024, lasiko ti awọn akẹkọọ naa pejọ ni ago mẹjọ abọ owurọ fun adura, ki awọn agbebọn ọhun to yabo ile ẹkọ naa lori alupupu, ti wọn si ji wọn gbe.

A gbọ pe ọjọ ori awọn akẹkọọ ọhun ko ju ọdun mẹjọ si marundinlogun lọ.

Awọn akẹkọọ naa, pẹlu awọn olukọ wọn ni awọn agbebọn ọhun ji gbe.

Iroyin ijinigbe ni iha Ariwa Naijiria kii ṣe iroyin tuntun amọ ijinigbe ọlọgọọrọ eeyan ti din ku laarin ọdun diẹ sẹyin titi di ọsẹ to kọja.