You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ wo bí ìsìnkú Wigwe, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ ṣe lọ
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ oṣu kẹta 2024 yii ni eto aisun alẹ onigbagbọ waye ni iranti ọga agba ileefowopamọ Access to doloogbe loṣu to kọja, Herbert Wigwe.
Aṣepọ leto naa, pẹlu bo sẹ jẹ ọjọ ati asiko kan naa ni wọn ṣeto ọhun fun iyawo Oloogbe, Chizoba pẹlu ọmọ wọn ọkunrin, Chizzy tawọn naa ku lọjọ kan naa pẹlu Wigwe.
Ọjọ Eti naa ni wọn gbe oku mẹtẹẹta de sorilẹ-ede Naijiria.
Awọn ẹbi, eeyan nla-nla lawujọ lo peju-pese si ile ijọsin RCCG, Tribe of Judah to wa ni Isiokpo, nijọba ibilẹ Ikwerre, ipinlẹ Rivers ti wọn ṣeto ikẹyin naa.
Awọn gomina bii Babajide Sanwo-Olu ati Dapọ Abiọdun naa wa nibi eto yii.
Bakan naa ni oniṣowo pataki nni, Aliko Dangote naa wa nibẹ.
Awọn yooku ni Nyesom Wike, Oloye James Ibori, Kayọde Fayẹmi ti i ṣe gomina Ekiti tẹlẹ, Wale Ẹdun to jẹ minista ọrọ okoowo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
‘Ẹ gbélé ayé ṣe rere’
Ninu ọrọ Pasitọ David Adeoye to dari eto naa, o rọ awọn eeyan lati huwa ire.
O ni ki wọn fasiko yii ronu nipa ohun ti Oloogbe Wigwe gbele aye ṣe, ki i ṣe fun Banki Access nikan, ati fun awujọ ọmọniyan pata.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹwaa, oṣu keji ọdun 2024 ni Oloogbe Wigwe, iyawo atọmọ rẹ ọkunrin, padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu agberapaa to waye ni California, nibi ti awọn eeyan mẹta mi-in naa ti padanu ẹmi wọn.