You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkunrin kan gún olùṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ́bẹ ní Kwara, ó tún yìnbọn mọ́ aráàlú kan
Kayeefi gbaa lo jẹ nini ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹta ọdun 2024 yii, nigba ti ọkunrin kan gun ọkan lara awọn oluṣọ ọgba ẹwọn Oke-Kura, ni ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara lọbẹ lori.
Bi ọkunrin naa ṣe gun-un lọbẹ tan lo tun bẹrẹ si i lọ ibọn oluṣọ ọgba ẹwọn naa mọ ọn lọwọ.
Níbi to ti n ṣe eyi, ni ibọn naa ti yin mọ ẹnikan to n ṣe iṣẹ apọtaya ọkọ nitosi ọgba ẹwọn naa.
Bo ṣe ṣẹlẹ gan-an
BBC Yoruba gbọ pe ni nnkan bi aago mejọ aarọ Ọjọbọ naa, ọkunrin kan ti ẹnikẹni ko mọ ẹyẹ to ṣu u n kọja lọ, ṣugbọn niṣe lo n gun awọn eeyan to pade lọna lọbẹ, bakan naa lo si n ba awọn kẹkẹ NAPEP jẹ.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣojú rẹ, sugbọn to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri, sọ pe bo ṣe de iwaju ọgba ẹwọn Oke-Kura, o sọ okuta mọ ọkọ anbulansi Ileesẹ ọgba ẹwọn naa.
"Ọkan lara awọn oluṣọ ọgba ẹwọn naa gbiyanju lati da a duro, sugbọn ọbẹ lo fi pade rẹ. O fi ọbẹ gun-un lori ati aya, lẹjẹ ba n ṣe bàlà.
"Ibi to ti n gbiyanju lati lọ ibọn gba lọwọ oluṣọ naa lo ti yinbọn mọ ara ilu to n lọ jẹjẹ rẹ.’’
Awọn to fi ara pa ọhun ti n gba itọju nile iwosan ijọba apapọ to wa niluu Ilorin.
BBC Yoruba ba Alukoro fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn Kwara (Kwara Command Correctional Service), Adegbulugbe Philip Olumide, sọrọ, o si fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
O ni oluṣọ to gun lọbẹ ni ASP Kabiru, to si n gba itọju lọwọ.
Ẹwẹ, alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Toun Adeyemi naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
Adeyẹmi sọ pe awọn furasi ọkunrin to gun eeyan lọbẹ to tun yinbọn mọ ẹnikeji yii, pe o ti lo aṣilo oogun, ori rẹ si ti n yi diẹdiẹ.
O ṣalaye pe afurasi naa ti wa lakata ọlọpaa bayii, awọn si n ṣewadii lori rẹ ati lori iṣẹlẹ naa lapapọ.