Olóòtú ìjọba kọ̀wé fipò sílẹ̀ lẹ́yìn tí fọ́nrán ohùn níbi tó ti kọnu ìfẹ́ sì obìnrin lu síta

Olootu ijọba orilẹede Peru, Alberto Otarola ni o ti kọwe fipo rẹ silẹ lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o n lo ipo rẹ lati fi ṣe iranlọwọ fun obinrin lati ma gba isẹ lọwọ ijọba.

Ọrọ yii lo bẹ sita lọsẹ to kọja nigba ti ileeṣẹ momaworan gbe fọnran ohun ibi awọn mejeeji ti n sọrọ jade.

Otarola, ẹni ọdun mẹtalelọgọta ni ọrọ ko ribi awọn akọroyin ṣe gbe sita.

Aarẹ President Dina Boluarte ni ki iwadii bẹrẹ lori isẹlẹ naa.

Gẹgẹ ohun ti iwe iroyin to safihan, awọn araalu n gbọ ohun obinrin to ba Olootu ijọba tẹlẹ sọrọ, iyẹn Yazire Pinedo, ẹni ọdun mẹdogun.

Iwadii fihan pe Pinedo ti gba isẹ meji lọwọ ijọba lọdun 2023, ti owo naa si jẹ 53,000 sol lọwọ ẹka ileeṣẹ ologun Peru.

Otarola ni minisita fun ileeṣẹ ologun ko to di Olootu.

Ninu fọnran ohun naa, wọn gbọ bi Otarola ṣe sọ nipa ifẹ rẹ fun obinrin naa, to si ni ko fi CV ransẹ si.

Sugbọn nnkan to wa ninu atẹjade ti Otarola fi lede ni pe ẹẹkan pere ni oun fi oju ri arabinrin Pinedo nibi ipade kan.

Sugbọn obinrin naa sọ fun ileeṣẹ momaworan Canal N lọjọ Isẹgun pe oun ati Olootu ijọba tẹlẹ ti fera fun igba diẹ tẹlẹ.

Awọn mejeeji ni ohun naa lo jẹ ohun ti awọn sọ ni ọdun 2021 saaju ki Otarola to di Olootu ijọba.

Sugbọn Aarẹ Boluarte ti ni ki Olootu ijọba naa suUre pada lati bib irinajo to wa ni Canada, ti Otarola si kọwe fipo silẹ.

O ni, “Awọn eeyan kan fẹ le mi kuro ni ijọba, ayederu ohun ni wọn fẹ fi ba orukọ mi jẹ,” Oratola sọ ninu iwe ikọwe fipo silẹ.

Lara awọn to fẹsun kan pe wọn lẹdi apupọ lati le kuro ni ijọba ni Olootu ijọba tẹlẹ, Martin Vizcarra.

Gẹgẹ bi ofin Peru ṣe gbe kalẹ, gbogbo ọmọ ile igbimọ aṣofin mejidinlogun ni yoo tẹle Olootu ijọba Otarola lati kọwe fipo wọn silẹ sugbọn Aarẹ ni anfani lati tun wọn yan pada to ba wu.