Ọkùnrin kan wọ gàù lẹ́yìn tó fọ́ kórópọ̀n aládùúgbò rẹ̀ níbi ìjà l’Eko

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Dominic Kenneth ti foju bale ẹjọ lori ẹsun ṣiṣe ipalara fun ara adugbo rẹ kan ni Ikorodu, niluu Eko.

Igbẹjọ naa n waye lẹyin ti afurasi ọhun fọ koropọn aladugbo rẹ kan lasiko ti wọn n ja.

Kenneth n jẹjọ ẹsun kan ṣoṣo, eyii to jẹ ṣiṣẹ ipalara fun ẹlomiran.

Afurasi naa ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Agbẹjọro ijọba, Christian Okonofua sọ fun ile ẹjọ naa pe afurasi ọhun wu iwa buburu yii lọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ladugbo Abdul Rasaq to wa ni Balogun, ni Ikorodu.

Okonofua ṣalaye niwaju adajọ pe Ọ̀gbẹ́ni Kenneth fa koropọn ọgbẹni kan ti wọn jọ gba ṣọọbu sagbegbe naa, Pascal Uche, lasiko ti ija bẹ silẹ laarin wọn yọ.

Gẹgẹ bii ohun ti Okonofua sọ, iwa naa lodi si abala 245 iwe ofin ipinlẹ Eko ti wọn ṣe lọdun 2015.

Ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria jabọ pe ẹwọn ọdun meje lo wa fun ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun to wa ni abala iwe ofin naa.

Adajọ to n gbọ ẹjọ naa, A.O. Onalaja ti gba beeli afurasi pẹlu owo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalenigba din mẹwaa naira (N250,000) pẹlu oniduro meji.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024.