You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèyàn kìí dá orin níbi tí wọ́n kò bá ti fẹ́ ẹ ni mo ṣe dá dúró nínú ìjọ Cele - Wòlíì Genesis Global
Oludasilẹ ile ijọsin Celestial Church of Christ, Genesis Global, Wolii Oladele Ogundipe ti ṣalaye idi ti ko fi ba awọn ijọ Cele yoo ku ṣe.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC, Wolii Ogundipe sọ pe oun ko tii kuro ninu ijọ Cele.
O ni nnkan to jẹ ko dabi pe oun ti kuro loju araye ni pe, oun ko si ni abẹ idari olu ìjọ kankan.
Ṣaaju ko to kuro ni abẹ adari to wa tẹlẹ, Oluṣọ àgùntàn Oladele Ogundipe sọ pe, awọn iji kan ja oun nibi i ọdun mẹta sẹyin.
Lara awọn iji to ni o ja oun, ni bi gbajugbaja akọrin Fuji, Wasiu Ayinde, ṣe lọ kọrin ninu ile ijọsin Genesis.
Yatọ si eyi, o ni alagba ijọ Cele kan naa tun joko si ori aga to wa fun Pasitọ agba ijọ Cele, lasiko ti ẹni naa lọ si Genesis.
"Iṣẹlẹ mejeeji mu ki wọn o ranṣẹ pe mi si ipade níbi ti wọn ti ba mi wi.
" Koda, wọn tako bi mo ṣe ma n ko owo ọrẹ fun awọn alaini ninu ijọ."
O ni nnkan to dun oun ju ni iwe ikọsilẹ ti wọn fun oun, eyi ti wọn tun fi si ori ayelujara.
Oluṣọ Ogundipe tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, Wasiu Ayinde funra rẹ lo wa si ṣọọṣi, to si kọ orin Ọlọ́run.
O ni oun ko le dẹkun lati ma a ní ifẹ Ayinde, nitori gbogbo eeyan ni Jesu funra rẹ ko mọra.
Lori bo ṣe ma n ko owo ọrẹ ti awọn ọmọ ijọ rẹ ba da fun àwọn eeyan lẹkọọkan, o ni oun ma n ṣe bẹ́ẹ̀ nitori igbagbọ oun ni pe kii ṣe gbogbo ọmọ ijọ lo n ri ounjẹ jẹ.
"O jẹ ọna lati ran iru awọn eeyan bẹẹ lọwọ."
Lori bo ya o ṣi wa ninu ijọ Celestial, Ogundipe sọ pe oun ṣi wa ninu ijọ naa, amọ kii ṣe labẹ oludari kankan.
O ni ti ìjọ naa ba ti ni olori agba ti wọn n pe ni Pastor Reverend, oun yoo darapọ.
Ọpọlọpọ igba ni ẹnu ti kun Oluṣọ Oladele Ogundipe, paapaa nitori ọna to n gba ṣe isin ninu ijọ to da silẹ.
Igbagbọ ọpọ eeyan ni pe iṣeṣi rẹ tako aṣa ati iṣe to wa ni Cele lati ibẹrẹ pẹpẹ.