Ìlú Ilorin kìí ṣe ìlú Mùsùlùmí, Ilẹ̀ Yorùbá ní - Iba Gani Adams

Aarẹ Ọnakankafo gbogbo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti bu ẹnu atẹlu rogbodiyan tọ bẹ silẹ laarin awọn onisẹse ati awọn Musulumni niuu Ilorin, to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara.

Aarẹ so eleyi niluu Osogbo ni gbadege asekagba Ọdun Osun-Osogbo, o ni igbesẹ awọn Musulumi si awọn onisẹse ni ko bujumu rara nitori ilẹ Yoruba ni Ilorin, ti ko yẹ ki ẹsin si ma fa rogbopdiyan.

"Ko boju mu rara, nnkan to ko ẹrẹ ba ilẹ Yoruba ni, ki eeyan wa tori ẹsin ma sọ pe ilu Ilorin, ilu awọn Musulumi ni

"N jẹ se Ilorin jẹ Mecca tabi Jebba tabi Saudi Arabia?

"Igba wo gan an ni ẹsin Islam wọ ilu Ilorin, ti wọn wa sọ pe ilu Ilorin jẹ ilu Islam."

Aarẹ jẹ ko di mimọ pe ẹni to sọrọ naa sita lo jẹ Ọjọgbọn agba ni fasiti ilu Ilorin, ti o si ku diẹ kato pe Ọjọgbọn naa kọ lati se iwadi to tọ ko to sọrọ naa sita.

"Laderin lo tẹ ilu Ilọrin duro, Laderin lo be Pati, Pati lo bi Alagbin, Alagbin lo bi Afonja, ti wọn si sekupa Afonja ni 1834 niluu Ilorin to fi di pe ẹẹya ti ko ki se ẹẹya Yoruba jẹ baga le wa lori.

"Kristẹni ati Musulumi lo wa niluu Ilorin, ki wa ni idi ti wọn ko fi aye silẹ fun awọn ẹlẹsin ibilẹ lati ma le se ẹsin ti wọn?

"Ẹ jẹ ki olunikaluku lo ọna to ba wu lati ba Olodumare sọrọ."

"Ole ni ẹni to ba ni oun fẹ ja fun Ọlọrun"

Aarẹ Gani Adam ni pupọ awọn ti wọn sọ sita pe awọn fẹ ja fun Ọlọrun lo jẹ ole, ti wọn ko si ni fẹ Ọlọrun.

"To ba ja fun Ọlọrun, to ba ri owo, n jẹ se o fẹ lọ ko idaji fun Ọlọrun ni?

"Gbogbo ẹni to ba sọ pe oun ja ija ẹsin ni ole, olojukororo, ainisẹ ni.

Aarẹ ni o se ni laanu pe pupọ awọn to ni awọn n ja fun Ọlọrun lo jẹ oni jibiti ẹda.

"Nitori awọn owo ti wọn fẹ gba lati Saudi, Iran lo mu pariwo ẹsin, ki se nitori pe wọn ni fẹ ẹsin yẹn denudenu,

"Nnkan ti wọn ma jẹ ni ko jẹ ki wọn gbọn."

"Mo bẹ gbogbo Yoruba, ọrọ alakakiti ẹsin, ẹ ma jẹ ko sẹlẹ"

Aarẹ ọna kankanfo rọ gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba lati ma fi aye gba ija alakati ẹsin, ki wọn si fi aye silẹ fun onikaluku lati se ẹsin to ba wu lọkan.

"Egun ni fun ẹlẹsin abalaye to ba lọ si Mọsalasi tabi Ile Ijọsin, to n lọ ni wọn lara

"Awọn alalẹ Yoruba ko le yọnu si irufẹ eeyan bẹ.

"Bakan ni egun fun ẹnikẹni to ba fẹ ni awọn ẹlẹsin abalaye lara nitori awọn lo ni ilẹ ki mejeeji to de.

"Ẹ pa Baba wa, a ko binu, ẹ tun jẹ Ọba, a ko binu, ẹ wa ni ki awọn ọmọ nilẹ ma se tiwọn

"Bi Ọba aye ko ba binu, Ọba ọọrun a binu."