You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gbajúgbajà òsèré tíátà, Baba Feyikogbon jáde láyé
Gbajugbaja oṣere tiata, Sunday Akinola, ti ọpọ mọ si Baba Feyikọgbọn ti jade laye ni ẹni ọgọrin ọdun.
Baba Feyikogbọn jade laye lọjọ Aje ọsẹ yii.
Agba oṣere ọhun ni o jẹ ilu mọka lọdun 1980 ati 1990- pẹlu gbajugbaja ere sinima ọsẹsẹ, Feyikọgbọn
Sinima ọhun ni wọn maa safihan lori momaworan NTA Channel 7, to si n lọ fun odidi ọdun meje.
Sulaimon Aremu, olorin ati olowe, ti ọpọ mọ si Ajobiewe lo kede ipapoda agba oṣere naa lori ayelujara.
A kole sọ iru iku to pa baba naa sugbọn lọdun 2019, o bere fun iranlọwọ owo lọwọ awọn araalu lẹyin to ni ipenija ọkan.
Lọdun naa, Baba Feyikogbon ni oun nilo Ọgbọn milọnu naira lati lọ si oke okun lati lọ ṣe itọju ara rẹ.
Wọn bi Baba Feyikogbon ni ọjọ kọkandilogun oṣu kẹsan an lọdun 1942.