Tinubu ní àlááfíà jù mí lọ lágọ̀ọ́ ara rẹ̀–Shettima

 Kashim Shettima tó fẹ́ ṣe igbákejì Bola Tinubu fún ìbò ààrẹ 2023 sọ pé Tinubu ní ìlera tó péye ju òun lọ.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣe lóríi Facebook lédè Hausa pẹ̀lú Bulama Bukarti, Ja'afar Ja'afar àti Abba Hikima, Shettima tó ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Borno rí sọ pé òun àti Tinubu ló yẹ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà yàn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àti igbákejì ààrẹ.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń káyà sókè lórí ìlera Tinubu tí ọ̀pọ̀ ń sọ pé bí olùdíje ààrẹ lábẹ́ APC ọ̀hún ṣe ń lọ sí òkè òkun, ìsọ̀rọ̀ sí rẹ̀ àti bí ọwọ́ rẹ̀ ṣe ń gbọ̀n nígbà míràn jẹ́ àpẹrẹ ààrùn Parkinson.

 Ṣùgbọ́n Shettima ní ìlera Tinubu dára tó láti tukọ̀ Nàìjíríà.

 "Asiwaju Bola Tinubu ní àlàáfíà tó péye. Ká pa ọ̀rọ̀ òṣèlú tì, ó ní àlàáfíà tó péye láti di ààrẹ Nàìjíríà.

"Kódà Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ní àlàáfíà jù mí lọ nítorí pé mo ní àisàn ìtọ̀ súgà (diabetes) àti ẹ̀jẹ̀ rúru (hypertension),

ṣùgbọ́n òun kò ní. Ọ̀rọ̀ ààrùn Parkinson tí àwọn èèyàn ń sọ gan àìróorunsùn ló ń fàá."

Shettima ní iṣẹ́ ọpọlọ ni Tinubu fẹ́ ṣe, kìí ṣẹ iṣẹ́ agbára.

Ó dárúkọ Theodore Roosevelt, Abdulaziz Bouteflika àti Daniel Arap Moi tó ṣe ààrẹ Amẹrika, Algeria àti Kenya tí wọ́n sì mú ìdàgbàsókè bá ọrọ̀ajé àwọn orílẹ̀-èdè wọn tòun ti pé wọ́n wà lórí kẹ̀kẹ́ àkàndá.