Iléẹjọ́ dá iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá lẹ́kun dídá àwọn ọlọ́pàá to bá lóyún dúró lẹ́nu iṣẹ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileẹjọ kan lorilẹede Naijiria ti gbe idajọ kalẹ lori ofin ileeṣẹ ọlọpaa to fi ofin de awọn obinrin ọlọpaa lori oyun nini , ti wọn si gba isẹ lọwọ wọn kete ti wọn ba ti lọyun.

Onidajọ ni ofin naa ko fi ẹsẹ mulẹ rara nitori pe awọn obinrin ọlọpaa nikan lo n ri jiya ofin naa, ti ko si de ọdọ awọn ọkunrin rara.

Obinrin ọlọpaa kan to padanu isẹ rẹ lọdun 2021 lo wọ ileeṣẹ ọlọpaa lọ si ileẹjọ lẹyin ti wọn gba isẹ lọwọ rẹ nitori pe oloyun, ti wọn si fun ni ni milọnu marun un naira, owo gba mabinu.

Ọlọpaa ọhun ti orukọ rẹ n jẹ, Omolola Olajide ni inu rẹ ko dun si igbesẹ naa, ko si ni ko ki ofin ya awọn ọkunrin lọtọ.

Nigba to gbe iadajọ rẹ kalẹ niluu Akurẹ, Adajọ Dashe Damulak ni ofin ileeṣẹ ọlọpaa ni ko ni ẹsẹ nilẹ rara, ti wọn si gbọdọ wọgile ni kiakia.

Damulak ni ofin orilẹede Naijiria ati ofin ajọ agbaye ko fi aye silẹ fun irẹjẹ laarin ọkunrin tabi obinrin. O ni o ṣe pataki ki obinrin ati ọkunrin jọ ni anfani to dọgba lẹnu isẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ko ti sọrọ lori idajọ naa sugbọn igbagbọ wa pe o ṣeṣe ki idajọ naa ṣe akoba fun awọn ileeṣẹ miiran to maa gba isẹ lọwọ obinrin kete ti wọn ba ni oyun.