Is Tinubu leaving APC?: Irọ́ ni pé Bola Tinubu fẹ́ kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Agbẹnusọ Aṣíwájú

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Leyin ipade ti awọn eekan ẹgbẹ All Progressives Party pe nilẹ Yoruba ni iroyin kan jade pe o ṣeeṣe ki Oloye Bola Tinubu paarọ ẹgbẹ oṣelu rẹ.

Alagba Bisi Akande to dari ipade yii ni ilu Eko si ti ni ẹnu awọn ko lori pe ki ẹkun Iwọ oorun Guusu ilẹ Naijiria fa oludije ipo aarẹ silẹ.

Ko sọ pato ẹni ti oludije yi yoo jẹ ṣugbọn wọn ni awọn yoo ṣi maa ṣe ipade loore koore.Fayemi ní òun ṣetán láti gbéná wojú àwọn alágbára tí kò jẹ́ kí Nàìjíríà tẹ̀síwájú

Bakan naa lo ni ki awọn oludije yooku pada wa to lẹyin ẹnikẹni to ba jawe olubori nidi idibo abẹle APC.Bí Jibrin ṣe kúrò ní ẹgbẹ̀ òṣèlú APC kò níi ṣe pẹ̀lú Bola Tinubu- Agbẹnusọ ìpolongo

Lori ọrọ ki awọn oludije maa ta abuku ara wọn, ipade naa sọ pe eyi ko bojumu ni paapa pe ọmọluabi lo yẹ ki awọn oludije ati alatilẹyin wọn jẹ.Ògo Naijiria yóò padà wá tí mo bá di Ààrẹ - Pasitọ Tunde Bakare

Se lootọ ni Bola Tinubu n fi ẹgbẹ APC sile?

Opo lo n sọrọ lori ayelujara pe lẹyin ti apero ti wọin ṣe ni ilu Eko ti faaye gba ẹnikẹni lati dije ni Tinubu ti n tun ero rẹ pa.

Sugbon ọkan lara awọn alatileyin Senatọ naa to n dije dupo labẹ asia ẹgbẹ APC ti sọrọsoke pe irọ to jina si ootọ ni.

Asiwaju sọ pe ẹru kò ba odo Bola Tinubu rara ninu ẹgbẹ APC

Bakan naa ni Honorebu Ayo Oyalowo, ọkan pataki ninu eekan ẹgbẹ APC to tun jẹ oludije ni Ogbomoso ti ni ọrọ ko ri bẹẹ.

Oyalowo sọ eyi ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile iṣẹ iroyin amohunmaworan Arise.

O ni pe Asiwaju lo ni iye nọmba akopa dẹligéèti to pọ julọ titi di oni yii.

Ati pe awọn akopa naa si ti fi Baba Bordellion lọkan balẹ pe didun ni ọsan yoo so fun un ti asiko idibo lati ayn oludije ba ti ya ni Abuja.