You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sister Kate: Mò ń wọ ìjáàbù kí àwọn okùnrin má bà ṣìnà ìjọba ọ̀run nítorí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí mi
Ajihinrere obinrin kan, Sister Catherine, ti ọpọ eeyan mọ si Sister kate ti sọrọ lori idi to ṣe n wọ ijaabu bo tilẹ jẹ pe kii ṣe Musulumi.
Obinrin naa sọ pe oun bẹrẹ si n wọ ijaabu nitori awọn aṣọ ti oun maa n wọ tẹlẹ maa n gbe bẹbẹrẹ idi oun sita, o si le dena awọn okunrin lati wọ ijọba ọrun.
Gẹgẹ bii oun to sọ, ọpọ eeyan lo ti maa n sọ fun oun tẹlẹ pe irufẹ awọn aṣọ ti oun maa n wọ ko bojumu gẹgẹ bii ọmọlẹyin Kristi, nitori o maa n gbe ara oun sita, o si le ṣe idena fun okunrin lọdọ Ọlọrun.
- Òní ni ọjọ́ mẹ́jọ ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi ni ìlú Oyo
- Bíbéli mi ló sọ pé kí n fẹ́ ìyàwó omidan mẹ́rin, kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀- Pásítọ̀
- Mínísítà Nàìjíríà, Abubakar Malami, tó wà nídí ẹjọ́ Sunday Igboho ti darapọ̀ mọ́ ìdíje dupò gómìnà Kebbi
- Ìdí nìyí tí Jonathan kò fi le díje dupò Ààrẹ Nàìjíríà mọ́
- Wo bí ètò Orò Ìje Oba Lamidi Adeyemi to wàjà ṣe lọ ní Oyo
Sister Kate ni ijaabu kii ṣe aṣọ awọn Musulumi gẹgẹ bii ọpọ eeyan ṣe gbagbọ, ṣubọn aṣọ awọn Kristẹni ti awọn Musulumi kan n yalo ni nitori o bojumu.
Ninu fidio kan loju opo Youtube rẹ lo ti fi ọrọ naa lede.
Mi o ki n ṣe Musulumi
Ajihinrere obrinin naa ni "Lati igba ti mo ti n wọ ijaabu ni ọpọ eeeyan ti maa n pe mi ni Musulumi, amọ mi o kii ṣe Musulumi."
"Lakọkọ, ọmọlẹyin Kristi ni mi, mo si ti di atunbi."
"Iwe mimọ sọ ninu iwe Mathew 5:28 pe Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀."
Arabinrin naa sọ siwaju si pe ni gbogbo igba ti oun ba n waasu ni awọn okunrin maa wo ibadi oun, eyii ti kii jẹ ki wọn tẹti si ọrọ Ọlọrun ti oun n ba wọn sọ.
O ni lọpọ igba ni awọn okunrin ma n sọ pe ibadi oun n da wọn lọrun.
- Ìjàmbá iná tó wáyé kò débi ibojì T. B. Joshua – Ilé ìjọsìn Synagogue
- Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Morenikeji Lasisi, olórí ẹrú tó ti bá Aláàfin mẹ́ta ṣiṣẹ́
- Ọmọ Ọba Charles kàn sí BBC lórí àjọ̀dún ọdún 90 tí BBC bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìròyín, Oríadé sọ̀rọ̀ pé..
- Ìj̀à tó bẹ́ sílẹ̀ ní Sudan ti gbẹ̀mí ènìyàn 200 lára àwọn tó sá àsálà fún ẹ̀mí wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Janjaweed
Sister Kate tẹsiwaju pe "Koda, Ọlọrun ti ba mi sọrọ loju ala mi pe ki n dẹkun ati maa da awọn okunrin lọrun, idi ree ti mo fi n wọ ijaabu."
Lẹyin naa lo gba awọn obinrin to maa n wọ aṣọ ati ṣokoto to maa n ṣi ara wọn silẹ nimọran lati dẹkun ṣiṣe bẹẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ko sọ pe ki awọn obinrin maa wọ ijaabu, o ni o yẹ ki wọn maa wọ awọn aṣọ ti yoo bo aṣiri ara wọn.