Easter Celebration: Olórí Celestial lágbàyéé ní kò yẹ kí Krìstíẹ́nì fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọdún àjíǹde

Àkọlé fídíò, Easter Celebration: Olórí Celestial ní Krìstíẹ́nì kò yẹ kó fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjíǹde

Ọjọ Kẹẹdogun osu kẹrin ọdun 2022 ni ayajọ ọdun Ẹti rere , ti wọn kan Jesu mọ agbelebu.

Lara awọn ọna ti BBC Yoruba fi fẹ sami ọjọ naa ni lati mọ ohun ti ọjọ Ẹti rere duro fun.

Gẹgẹ bi Ẹsin Kristiẹni ti laa kalẹ, ọjọ Ẹti rere yii ni wọn kan Jesu Kristi mọ agbelebu.

Ọdọọdun si ni awọn ọmọlẹyin Kristi maa n sami ọjọ naa lọdọọdun lati fidi igbagbọ wọn ninu iku ati ajinde Jesu Kristi mulẹ.

“Bi wọn ko ba kan Jesu mọ agbelebu ni, asan ni ẹsin Kristiẹni”

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, ojisẹ Ọlọrun kan, tii se asaaju ijọ Celestial jakejado agbaye, to kalẹ si orilẹẹede Benin, Ẹni ọwọ Akande Adeogun sọ nipa pataki ọjọ Ẹti rere.

Ẹniọwọ Adeogun ni bi wọn ko ba kan Jesu Kristi mọ agbelebu ni, ko si jinde ni ọjọ kẹta, asan ni igbagbọ awọn Kristiẹni ko ba jẹ.

O ni iku ati ajinde Jesu yii lo fun ẹsin igbagbọ ni itumọ gidi, to si jẹ ka mọ pataki rẹ ati idamọ rẹ laarin awọn ẹsin yoku.

Ojisẹ Ọlọrun naa wa salaye pe akoko pataki ni ọdun ajinde jẹ, ko si yẹ ki ọmọlẹyin Kristi kankan fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọdun naa.

Adeogun wa yan pe awọn asọtẹlẹ to ti waye saaju nipa iku ati ajinde Jesu Kristi gẹgẹbi Olugbala araye ni idi pataki ti Kristiẹni fi le fi ọwọ sọya pe awọn n lọ sọrun rere.