You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kemi Afolabi: N kò mọ ohunkohun nípa ayédèrú ojú òpó Facebook tó ń bèèrè ìrànwọ̀ lórúkọ mi
Ogun awitẹlẹ kii pa arọ, eyiun arọ to ba gbọn, bẹẹ si ni ta ba n sunkun, a maa riran.
Eyi lo mu ki gbajugbaja osere tiata nni, Kemi Afolabi figbe sita pe ki awọn ololufẹ oun sọra gidi, ki wn maa baa ko sọwọ awọn onijibiti lori ayelujara.
Kemi Afolabi lo kede lọjọ Ẹti to kọja pe aisan Lupus n ba oun finra eyi to n ro oun ninu egungun ara, ti awọn dokita si ti kede pe o ni oun ko ni ju ọdun mẹrin lati lo loke eepẹ.
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti gbajúmọ̀ míì tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
- Wo àwọn nǹkan tó le fa lupus - àìsàn tó ń bá Kemi Afolabi fínra
- Òṣèré tíátà, Kemi Afolabi dùbúlẹ̀ àìsàn ní ìlú Mecca
- Wo àwọn òṣèré tíátà tó ti fún Kemi Afolabi lẹ́bùn àtàwọn tó ń kíi lẹ́yìn tó kéde àìsàn rẹ̀
- Adigunjalè kọlu Kemi Afolabi, wọ́n fi àdá ṣá òun àti awakọ̀ rẹ̀
- Òṣèré tíátà, Kemi Afolabi fi ohùn ìdúpẹ́ ránṣẹ́ láti Meccah fún àdúrà ọmọ Nàíjíríà
Osere tiata naa fikun pe owo to to miliọnu kan naira ni oun n na lojumọ lati ra oogun ati se ayẹwo lori aisan naa, ti oun si ti ta lara dukia oun.
Idi si ree ti ọpọ awọn akẹẹ gbẹ rẹ lagbo tiata atawọn ololufẹ rẹ se n rọjo ẹbun ati adura le lori, lati seto iranwọ fun lori itọju ara rẹ.
Amọ nibayii, Kemi Afolabi ti wa kede pe oun kẹẹfin awọn ọbayejẹ ẹda kan, ti wọn n beere iranwọ ni orukọ oun lori ayelujara lai jẹ pe oun mọ nipa rẹ.
Ẹ wo ọna ti Kemi Afoalabi ni fẹ gba lu araalu ni jibiti lorukọ oun:
Ninu ikede to gbe soju opo Instagram rẹ, osere tiata naa gbe aworan ohun ti awọn onijibiti naa gbe soju opo Facebook ni orukọ rẹ sita.
Ninu aworan naa ni wọn gbe aworan kemi Afolabi si, ti wọn si kọ orukọ rẹ soju opo Facebook tuntun ti wọn si ni orukọ rẹ naa, ti wọn pe ni Kemi Afolabi Adedipe.
Iwadii fihan pe ilu Eko ni awọn onijibiti naa ni awọn wa, ti wọn si fi nọmba kan soju opo naa fun awọn eeyan to ba fẹ pe wọn.
Kemi Afolabi ni ọrọ to sọ labẹ aworan naa ni "O ti de etigbọ mi pe awọn ọbayejẹ kan n lo anfaani ipo ti mo wa lati lo orukọ ati aworan mi loju opo Facebook.
Awọn onijibiti naa si se eleyi lai jẹ pe mo mọ nipa rẹ tabi gba asẹ lọwọ mi lati se bẹẹ.
Oju opo Facebook mi tootọ ni Kemi Afolabi/Afolabi Kemi, kii si se Kemi Afolabi Adedipe.
Mo wa n rọ ẹyin ololufẹ mi lati mase naani awọn iroyin to ba n jade loju opo awọn onijibiti naa.
Ẹ ri daju pe awọn eeyan ko ko sọwọ awọn gbajuẹ yii nidi iwa jibiti ti wọn n hu."