Ilé ẹjọ́ da ẹjọ́ tí Uche Secondus pè láti dá ìpàdé gbogbogbò ẹgbẹ́ PDP dúró nú

Ile ẹjọ kotẹmilọrun kan niluu Port Harcour ti dajọ pe ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu PDP gbọdọ tẹsiwaju lọjọ Satide gẹgẹ bi wọn ṣe gbero rẹ tẹlẹ.

Adajọ G.O. Kolawole to dari igbimọ ile ẹjọ naa da ẹjọ ti alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Uche Secondu, pe lati wọgi le ipade naa nu.

Ṣugbọn ile ẹjọ ọhun sọ pe ẹjọ keji ti Secondus pe lori bi wọn ṣe yọ ọ kuro nipo alaga ẹgbẹ naa yoo tẹsiwaju.

Pẹlu idajọ yii, awọn aṣoju ẹgbẹ PDP to ti korajọ si gbagede Eagles Square yoo tẹsiwaju ninu ipade ti wọn fẹ ṣe.

Ipade naa yoo waye lọjọ Satide, ọgbọn ọjọ, ati ọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 yii.

Ko din ni ẹgbẹrun mẹta abọ awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ti yoo peju sibi ipade ọhun, nibi ti wọn yoo ti yan awọn adari tuntun fun ẹgbẹ naa.

Ọdun 2017 ni Secondus gori alefa gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin to ti kọkọ wa lori oye naa gẹgẹ bii alaga fidihẹ laarin ọdun 2015 si 2016.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ilé ẹjọ́ sún ìdájọ́ síwájú lórí ẹjọ́ tí Secondus pè láti dá ìpàdé gbogbogbò ẹgbẹ́ PDP dúró

Ile ẹjọ kotẹmilọrun kan niluu Port Harcourt ti sunidajọ rẹ siwaju lori igbẹjọ ti alaga gbogbo ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Uche Secondus pe tako bi ẹgbẹ naa ṣe ni ko lọ rọkun nile.

Uche Secondus tun n rọ ile ẹjọ naa lati wọgile ipade gbogbogbo ti ẹgbẹ naa mura lati ṣe lọgbọn ọjọ ati ọjọ kọkanlelgbọn oṣu yii tẹsiwaju.

Ṣaaju ni PDP ti kọkọ mu ọgbọn ọjọ ati ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu yii fun ipade ti wọn yoo ti yan awọn alaṣẹ tuntun fun ẹgbẹ oṣelu naa lẹyin rogbodiyan to waye ninu ẹgbẹ ọhun ṣaaju, nibi ti wọn ti fi ọwọ osi juwe ile fun igun ẹgbẹ naa ti Secondus n dari.

Ṣugbọn igbesẹ naa ko dun mọ Secondus ninu, eyii to mu ko pe ẹjọ lori bi wọn yọ nipo alaga, ati pe ki ile ẹjọ da ipade naa ti yoo waye duro.

Ṣugbọn ile ẹjọ ti wa sọ pe ẹjọ to pe ko lẹsẹ nilẹ.

Ni bayii, ipade ẹgbẹ oṣelu naa yoo waye lọjọ ti wọn ti da ṣaaju.

Ọdun 2017 ni Secondus gori alefa gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin to ti kọkọ wa lori oye naa gẹgẹ bii alaga fidihẹ lati ọdun 2015 si 2016.