Babe on Whatsapp Case: Sikiru Jamiu dèrò iléẹjọ́ torí ó pe ìyàwó oníyàwó ní ‘Babe’ ní Whatsapp

Yoruba ni iwọ oju kokoro, nibo lo ba olowo rẹ de?, to si dahun pe oun yoo sin de pẹrẹ-pẹrẹ ilẹ.

Bo se ri gan ree pẹlu ọkunrin kan, to ri oju tan, to wa n wa airoju kiri lati ipasẹ sina sise.

Ọkunrin ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Sikiru Jamiu lo ti wọ gau lori bo se kan si iyawo ile kan, to si n pe ni orukọ to jẹ mọ ti ololufẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jamiu tii se olugbe ilu Ijebu Ode, ni ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti wa fẹsun kan pe o n pe iyawo ile naa, Opeyemi Adegbesan ni "babe" eyi to kọ soju opo ikansiraẹni Whatsapp obinrin naa.

Nibayii ọkunrin naa ti n kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ lori idi to fi san iru asọ yii se oro pẹlu iyawo oniyawo.

Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ tileesẹ ọlọpaa pe, eyi ti officialsamolatunji1 fi si oju opo Instagram rẹ, iwe naa ni wọn kọ ni kootu majisireti ti Ijebu Ode, ti wọn kọ ni ogunjọ osu Kẹwa ọdun 2021 ti sọ.

Jamiu sẹ ẹsẹ naa ni aago mẹjọ kọja isẹju meji ni ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹsan Ẹsun naa si ni wọn lo seese ko da omi alaafia to wa ninu igbeyawo obinrin naa ati ọkọ rẹ, Akintunde Adegbesan ru.

O si seese ki Jamiu fi asọ penpe roko ọba fun odidi osu kan gẹgẹ bi iwe ofin to n dena iwa ọdaran nipinlẹ Ogun ti laa kalẹ.

Iwe ipẹjọ naa sọ bayii pe "iwọ Sikiru Oluwaseun Jamiu ni opopona Fidipote nilu Ijebu Ode hu iwa to le da igbeyawo ru laarin Akintunde Adegbesan ati aya rẹ, Opeyemi Adegbesan.

Ohun to kọ soju opo Whatsapp obinrin naa, tii se 'Good Morning Babe' pẹlu nọmba ipe 08059491562 ati 08138868837 si lo ni ijiya labẹ ofin.

Isẹlẹ yii lo ti n gbona lori ayelujara, ti oniruuru eeyan si n sọ ero wọn nipa isẹlẹ naa.