Gunmen Attack Church: Ọjọ́ Àìkú ní agbébọn ya wọ ṣọ́ọ́ṣì lásìkò ìsìn, ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn di àwátì

Se ni ibanujẹ tun dori awọn agba kodo ni ipinl Kaduna lọjọ Aiku, nigba tawọn agbebọn tun ya wọ ile ijọsin onitẹbọmi Baptist kan to wa ni ilu Kakau Daji.

Awọn onisẹ ibi yii lo gbẹmi olujọsin meji nigba ti wọn ji ọgọọrọ eeyan lọ.

Aarẹ fun ipade ajọ nla ijọ onitẹbọmi, Ẹni ọwọ Ishaya Jangado to fidi isẹlẹ yii mulẹ tun tọkasi pe oun ko tii le sọ iye eeyan tawọn ajijigbe ọhun ko lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bo ti salaye, aarọ ọjọ Aiku ni isẹlẹ naa waye amọ ijọba ipinlẹ Kaduna ati ileesẹ ọlọpaa ko ti fesi lori rẹ.

Lero ti ẹni ọwọ Joseph Hayab ti ẹgbẹ agbarijọpọ awọn ọmọlẹyin Kristi CAN, isẹlẹ naa lo tun n fidi eto aabo to dori kodo ni Naijiria mulẹ.

O ni se ni wọn n pa awọn araalu bii adiẹ, to si jẹ pe atẹjade lati bawọn kẹdun nikan ni wọn jẹ ijọba, ọjọ si ti pẹ tawọn ikọ afẹjẹwẹ yii ti n soro fun awọn olujọsin.

Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi ọwọ ofin mu afurasi ọmọ onilẹ mẹta ti wọn yabo abule Jegede lagbegbe Igbesa ni ijọba ibilẹ Ado Odo pẹlu oriṣiiriṣii ohun ija oloro ti wọn fi ṣe awọn eeyan lọṣẹ.

Ọjọ Aje ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹwaa ni wọn mu Adewale Muyibi, Kamoru Ayodele ati Taofeek Ogundele.

Awọn agbofinro morile abule naa lẹyin ti awọn eeyan kan tawọn lolobo pe, awọn ọmọ onilẹ ọhun ti da ibọn bolẹ nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ le ní ìfẹ̀ síí:

Ọga agọ ọlọpaa lagbegbe Agbara, Saleh Dahiru, lo ṣaaju awọn ọlọpaa lọ si abule naa, nibi tawọn ọmọ onilẹ naa ti yinbọn fun eeyan mẹfa.

Awọn ọlọpaa lo doola eeyan mẹfa naa, Sunday Okorie, Shoneye Akeem, Lakan Oloyede, Jimoh Musibau Akande Oyedeji ati Hamzat Idiris ti wọn si tun gbe wọn lọ si ile iwosan.

Lẹyin ọ rẹyin, mẹta lawọn ọlọpaa ri mu ninu awọn ọmọ onilẹ naa nigba tawọn to ku fẹsẹ fẹ.

Oriṣiriṣi ọta ibọn lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ awọn ọdaran naa labule Jegede.

Ẹwẹ, kọmiṣọnaa ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankole ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi ọmọ onilẹ naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwadii.

Bakan naa ni ọga ọlọpaa Ogun paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa ṣe awari awọn to salọ ninu awọn ọdaran ọhun.

CP Bankole wa kilọ fawọn gbalẹ gbalẹ lati ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ nipinlẹ Ogun, bi bẹẹ kọọ, ilẹ yoo ga ju wọn lọ.

O ni oun ko le laju silẹ ki awọn kọlọnbiti ẹda kan maa da ilu ru nipinlẹ Ogun.