You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oluwo: Àwọn adarí ẹ̀sìn Musulumi ṣe ayẹyẹ fún 'Grand Mufti, Oluwo kò yọjú
Awọn adari ẹsin Musulumi kan ṣabẹwọ si ilu Iwo, nipinlẹ Osun lati ṣe moriya fun Sheik Daood Imran Molaasan ti wọn yan gẹgẹ bi ''New Grand Mufti'' ilẹ Yoruba.
Oluwo ti ilu Iwo, Oba AbdulRasheed Akanbi lo yan Sheik naa ni oye ẹsin Musulumi.
Eleyii ti fa ariyanjiyan, ti o si ti di ọrọ ileẹjọ pẹlu idajọ pe Oluwo ko ni aṣẹ lati yan aṣoju ẹsin Musulumi, ati wi pe ko da ọwọ duro lori iyansipo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Iyorchia Ayu dí Alágá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn ọmọ ìgbimọ̀ tó kù rè é
- Ìdìbò abẹ́nú APC Oyo pàpà wáyé lẹ́yìn tí jàǹdùkú mú alága ìbò abẹ́nú nígbèkùn
- Agbébọn ṣe ń gba owò ilẹ̀ ní Ariwa, agbèrò ń gbà ní gúúsù, kò sí ìyàtọ̀ - Lai Muhammed
- Ìjíròrò tó wáyé láàrín Bola Tinubu àti Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo, ohun tí a rí gbọ́ nípa rẹ̀ nìyí
- Kí ló mú ọkùnrin kan fi ejò Sèbé olóró pa aya rẹ̀ lójú oorun?
- Wo ọ̀nà tí o lè gbà borí àìsàn rọpá-rọṣẹ̀ tó ń pa ọ̀gọ̀rọ̀ lágbáyé
- Omi ìdọ̀tí atí ''biscuit'' la jẹ fún ọjọ́ méje - Àwọn àgùnbánírọ̀ sọ ìrírí wọ́n lọ́wọ́ ajínígbé
- Wo bí àwọn agbófinró ṣe ya bo ilé Onídájọ́ Mary Odili pẹ̀lú àwọn ohun tuntun tó súyọ
- Iléẹ̀kọ́ fásitì OAU ṣí padà lẹ́yìn ikú akẹ́kọ̀ọ́, Aishat Adesina tó fa ìfẹ̀hónúhàn
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó fẹ́ da ìdánwò rú
Ajọ League of Imams and Alfas lo gba ileẹjọ lọ lati pata si igbese Oluwo lati yan ẹnikẹni si ipo Musulumi.
Amọ lẹyin wakati diẹ ti idajọ akọkọ naa waye, ni ileẹjọ giga tilu Osogbo tun pasẹ pe oun gbẹsẹ le asẹ akọkọ to waye saaju lati tako iyansipo Grand Mufti naa, to si ni ki wọn tẹsiwaju lati fi oye naa jẹ.
Iwe asẹ ile ẹjọ naa ti Oluwo fi sọwọ sile isẹ BBC Yoruba fihan pe ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn osu kẹwa ọdun 2021 ni ileẹjọ pasẹ naa.
Amọ, n ṣe ni awọn eniyan pejọ si ibi ayẹyẹ naa ni opin ọṣẹ lati yọ pẹlu oloye naa, amọ Oluwo ko yọju sibẹ.
Nibi ayẹyẹ naa ti ẹgbẹ awọn Musulumi ni ilu Iwo ati Jamaát Taáwunil Muslimeen ṣe agbatẹru fun, ni Molaasan ti salaye pe Oluwo ti fi oun jẹ oye naa ki ọrọ ileẹjọ to de ilẹ.
Malaasan to jẹ aarẹ ẹgbẹ Musulumi, Jama'atu Ta'awunul Mumineen ni oun yoo wa ọna lati ṣepade pẹlẹ-putu pẹlu awọn to n fi apa janu lati ri pe alaafia ati ifimọṣọkan waye laarin awọn musulumi.
O ni awọn yoo jiroro lori ohun ti ẹsin Musulumi jẹ, ti awọn yoo si pe awọn adari ẹsin Musulumi Sunni ati Sufi lati ṣiṣẹ pọ lori ilọsiwaju ẹsin wọn.
Awọn to pejọ si ibi ayẹyẹ naa ni Waziri ilẹ Yoruba, Sheik Yaqoob Muhammad AbdulBaqi, awọn adari ẹsin Musulumi lati ipinlẹ Oyo, Ogun, Kwara ati ilu Eko.
Bakan naa ni awọn adari ẹsin naa ṣabẹwọ si Oluwo ni afin ọba, nibi to ti gbadura fun wọn to si ti gba wọn niyanju lati ṣiṣẹ pọ ninu irẹpọ.
Ilé ẹjọ́ ṣẹ́ eegun ẹ̀yìn Oluwo lórí yíyan Grand Mufti Yorùbá, àmọ́ Oluwo ní òun yóo fi oyè náà jẹ dandan
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, awuyewuye ko ti tan lori bi Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba AbdulRasheed Akanbi ṣe yan Sheik Dawood Imran Molaasan gẹgẹ bi Grand Mufti ilẹ Yoruba.
Ni Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2021 yii ni ile ẹjọ giga kan niluu Osogbo paṣẹ pe Sheikh Molaasan ko gbọdọ pe tabi ri ara rẹ gẹgẹ bi Grand Mufti ilẹ Yoruba mọ titi ti ẹjọ ti wọn pe e yoo fi yanju.
Ẹgbẹ awọn lmam atawọn aafa lo gbe ọrọ naa lọ si ile ẹjọ lati da Oluwo duro lori ati yan Sheik Molaasan loye.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Cotonou tẹ akọ̀royìn tó fi fọ́nran ohùn Sunday Igboho síta
- Gbẹgẹdẹ fẹ́ gbiná láàrín Oluwo àtàwọn ìgbìmọ̀ Ìmáàmù àti Àlfáà ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ní Oluwo ń kọjá àyè rẹ̀
- 'Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo'
- Obìrin tó ń ta omi inú ọ̀rá subú pẹ̀lú ọmọ lẹ́yìn torí ebi
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
- Wo orúkọ tuntun tí Facebook yóò má jẹ́ láti àkókò yíì lọ
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Seyi Makinde kò láṣẹ láti fi ẹ̀rọ CCTV sí ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí aya aláya lórí Whatsapp
BBC Yoruba kan si Oluwo lori ọrọ yii, ṣugbọn kabiyesi ko fesi amọ Oluwo ni ki a ba Sheikh ti oun fi joye gan an sọrọ.
Sheikh Molaasan sọ fun wa pe oun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn Imam ati aafa to pe ẹjọ yii, nitori naa, wọn ko le lo ofin kankan le oun lori.
O ṣalaye pe awọn agbẹjọro oun naa ti wa lori ọrọ yii, wọn yoo si pade nile ẹjọ pẹlu awọn to pe oun lẹjọ.
Lori ọrọ ti ẹgbẹ Imam atawọn aafa to sọ pe ko tọ si ọba alaye lati yan ẹnikẹni si ipo Mufti, Sheikh ni ọba laṣẹ lati yan Mufti gẹgẹ bi o ti laṣẹ lati yan Imam.
''Ẹgbẹ awọn baba wa kan ninu ẹsin Islam ni awọn to pe wa lẹjọ lori oye Mufti ti Oluwo fi mi jẹ.
A kii ṣe ẹgbẹ kan naa, a kan jọ jẹ ẹleṣin Islam ni ati pe ti ile ẹjọ ba da ẹjọ ti ko ba tẹ wa lọrun, a ni anfani lati pe ẹjọ kotẹmilọrun.
Emi o bawọn ṣe ẹgbẹ wọn, ẹgbẹ Ta'awun musulumi ni ẹgbẹ tiwa eleyii ti a si forukọ silẹ pẹlu ajọ C.A.C.
Gbogbo mọṣalaaṣi wa ni ko si labẹ awọn Imam yii, bakan naa ofin ko fawọn Imam lagbara lati yan ẹnikẹni sipo.
Ati pe awọn Imam to pe mi lẹjọ yii ko fi orukọ silẹ pẹlu ajọ ijọba C.A.C.
Oluwo ti fi emi jẹ oye yii tipẹ, awẹjẹ-wẹmu lasan an ni a fẹ ṣe lọjọ Abamẹta ki ẹgbẹ Imam yii to pe mi lẹjọ,'' Sheikh Molaasan
Akeugbagold rọ Oluwo lati fi ọrọ oye ẹsin Islam silẹ fawọn Alfa àti Imaamu:
Ẹwẹ, Sheikh Akeugbagold Taofeeq ti rọ Oluwo lati maa dasi ọrọ oye jijẹ ninu ẹsin Islam.
Akeugbagold sọ fun BBC Yoruba pe niṣe lo yẹ ki Oluwo fi awọn aafa silẹ lati maa yan eeyan sipo fun ra wọn.
''Awọn ọba ni wọn maa n yan Imam si ipo nilẹ Yoruba, amọ o le ma ba ẹsin Islam mu.
Amọ, awọn aafa lo yẹ ki wọn maa fawọn eeyan jẹ oye ninu ẹsin Islam, mo si mọ pe awọn aafa ilu Iwo mọ bẹ.
Ṣugbọn emi maa gba baba wa Oluwo ni imọran lati fi ọrọ ẹsin silẹ fawọn aafa.
Ki wọn ma ba wọn fa tabi ba wọn du ohun kohun.
Lẹyin Imam tawọn ọba maa n yan sipo, wọn kii dasi awọn oye yoku ninu ẹsin Islam,'' Akeugbagold lo sọ bẹẹ.
Oluwo ni dandan oun ti fi oye naa jẹ na, iwuye naa yoo waye:
Ninu atẹjade kan ti Oluwo fisita lọjọ Ẹti, tii se ọjọ keji ti idajọ naa waye, o ni oun n tẹsiwaju lọla ọjọ Satide lati se ayẹyẹ iwuye Grand Mufti Yoruba jẹ.
Ọba alaye naa ni lẹyin ifikunlukun to yẹ, awọn eeyan ti ọrọ naa kan ti pahunpọ fọwọsi yiyan Sheik Dawood Imran gẹgẹ bii Grand Mufti tilu Iwo.