You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀nà méje rèé láti borí àìsàn rọpá-rọṣẹ̀ tó ń pa àwọn ènìyàn ní àgbáyé!
Ajọ eto ilẹra ni Naijiria, Nigeria Medical Association, (NMA) ti sọ wi pe o kere tan miliọnu mẹtala eniyan lagbaye lo n ni aisan rọpa-rọṣẹ.
Ṣaaju ni alaga Ajọ NMA ni ipinlẹ Kwara lọdun 2021, Ọjọgbọn Baba Issa ti fi ikilọ lede lati ṣayajọ Ọjọ aisan rọpa-rọṣẹ lagbaye, World Stroke Day pe awọn eniyan nilo lati maa ṣetọju ara wọn lati dena rọpa-rọsẹ.
NMA ni o kere tan eniyan miliọnu mẹtala ni yoo ni aisan rọpa-rọṣẹ lagbaye, ti o kere tan eniyan miliọnu marun un yoo ba arun naa lọ.
O salaye pe ikede yoo mu ki awọn eniyan kiyesi aisan yii lagbaye, nitori o ti fẹ di aisan tile-toko.
Bakan naa ni wọn fi kun pe aisan rọpa-rọṣẹ ni o n pa awọn eniyan julọ ni agbaye ati pe awọn to ti da dubulẹ si ti le n si ni ojoojumọ.
Ohun meje ti o le ṣe lati bori aisan rọpa-rọṣẹ ni yii...
- Ẹjẹ Riru: Ri daju pe o ko ni aisan ẹjẹ riru to kọja 120/80 nipa ṣiṣe adinku lilo iyọ ninu ounjẹ rẹ, jijẹ eso ati ẹfọ loorẹ-koore.
- Din sisanra ku: ọkan lara awọn aisan to n fa ẹjẹ riru ni ara sisan lasan ju, eleyii to n fa aisan rọpa-rọṣẹ.
- Ṣiṣe ere idaraya ni iwọn bi ọgbọn iṣeju lojoojumọ yoo mu adinku ba aisan ẹjẹ riru to le fa aisan rọpa-rọsẹ.
- Ọti mimu: Ko dara lati mu ju ọti igo kan lọ lojoojumọ nitori o le fa aisan ni ọkan eniyan ati ọpọlọ.
- Aya Jija: Ri pe o tọju aisan ki aya ma a ja nigba gbogbo, ki eemi maa ja geere nipa ṣiṣe ayẹwo ara ati oogun oyinbo ti yoo tọju rẹ.
- Aisan Suga: Aisan suga maa n ba awọn eroja ara to maa n gbe ẹjẹ kiri ara paapaa lọ si ọpọlọ ati ọkan.
- Siga Mimu: Ṣiga mimu maa n fa ki ẹjẹ o dipọ paapaa ninu iṣan, eleyii to le fa aisan rọpa-rọsẹ.
Bi o ṣe le da aisan rọpa rọṣẹ mọ ti o ba n bọ;
- Ti ẹgbẹ kan oju ba wọ si ẹgbẹ kan ti eniyan ba fẹ rẹrin.
- Ti o ba na apa mejeeji soke, ẹyọkan ma a jabọ ninu ẹ
- Ti ọrọ ẹnu eniyan ko ba dede ja gẹre mọ.
- Ori fifo loore-koore to kọja ala
- Ki ẹgbẹ kan maa dun eniyan kọja ala
- Aile dede riran daradara
- Ki ẹsẹ maa yẹ ti eniyan ba n rin
Kiakia ni ki ẹ pe ileewosan pajawiri ti o ba ri awọn ami wọn yii.