Mọ̀ nípa ẹgbẹ́ kan tó wà fún àwọn obìnrin tí kò fẹ́ l'ọ́mọ láyé

Iye awọn obinrin to ti pinnu pe awọn ko fẹ lọmọ laye lo ti n gboro si bayii, ti iye awọn ọmọ ti wọn n ba si aye si n dinku.

Ọpọlọpọ idi ni wọn ni o fa igbesẹ yii lati ori owo itọju ọmọ ati kudiẹkudiẹ ilera ati awọn idi mii to mu obinrin pinnu pe oun ko fẹ lọmọ laye.

Ileeṣẹ BBC ba awọn obinrin to jẹ ọmọ ẹgbẹ Bristol Childfree Women sọrọ, ẹgbẹ yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ le ni ọdẹgbẹta ni ye, ti awọn obinrin kan da silẹ fun awọn obinrin to pinnu pe awọn ko fẹ lọmọ laye.

Caroline Mitchell ni oun ti mọ tipẹ pe oun ko fẹ bimọ ati pe oun ko gbaradi fun ipo ọmọ bibi.

Obinrin naa, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta to n gbe pẹlu ọkọ rẹ ni Brislington, Bristol ni igbesẹ yii ko fa irẹwẹsi si ọkan oun rara nigba ti oun wa ni ọmọge, ti awọn ibeere ti ọpọ ọrẹ ati mọlẹbi n bere lọwọ oun ko si jẹ nnkan tuntun.

“O da bi pe mo da yatọ nitori igbesẹ mi.” O ni.

“Mo ro pe awọn eeyan ko tẹwọgba ohun ti mo ri ati iriri ti mo ni to jẹ ki gbe igbesẹ naa.”

Ni oju Caroline, awọn abiyamọ ni wọn da agbegbe fun un.

“O ma ri pe wọn yọ ẹ kuro ninu ọpọ nnkan to n lọ laye.” o salaye.

“O nira fun mi lati pade eeyan nitori gbogbo nnkan da lori awọn obinrin ti ẹ ba ba pada ni ẹnu ọna ile ẹkọ, to mu ọmọ wa ile ẹkọ.”

Caroline ni oun gbagbọ pe awọn obinrin to ni ọmọ gbagbọ pe wọn da gbogbo agbaye si lẹ fun awọn obinrin ti ko ni ọmọ.

Ọpọ awọn eeyan to sumọ Caroline ni wọn ni ọmọ.

O tẹsiwaju pe o tẹ oun lọrun bi oun ṣe wa sugbọn nigba mii, oun ma bimu lori igbesẹ oun.

Caroline ni eyi da lori igbagbọ awọn si obinrin pe o gbọdọ lọmọ laye.

"Ida 51% obinrin to le ni ọdun 30 ni ko ti bi ọmọ ni England ati Wales"

Lọdun 2022, iye awọn obinrin ti wọn le ni ọgbọn ọdun ti wọn ko bimọ lu ori ayelujara.

Ida aadọta obinrin ti wọn bi ni England ati Wales ni ọdun 1990 ni wọn wa ti wọn ko ni ọmọ ni ọdun 2020.

Gẹgẹ bi Ọfisi National Statistics ṣe kede, igba akọkọ ti iru eyi ma waye laarin awọn obinrin.

Megan Stanley, wa lati ilu Oxfordshire, to si n gbe ni Bristol ni o da oun loju pe ko le kabamọ igbesẹ ti oun gbe pe oun ko fẹ bi ọmọ.

Nigba to n sọrọ nipa nnkan oṣu to ma ṣe gẹgẹ bi obinrin, Megan ni ohun to buru ni ki obinrin maa la irọna yii kọja ni oṣooṣu ni ago ara.

Fiona Powley ni lati ọmọ ọdun mejila ni oun ti mọ pe oun ko fẹ bimọ nitori bi o ṣe ri inira ti iya rẹ lakọja.

“Iya mi ko gbadun titọmọ kekere. Iya mi ko ri nkankan lati ṣe si gẹgẹ bi a wa ṣe wa nnkan se si bayii.

“Mo kan ro pe Abiyamo ko ni igbadun kankan ninu, ọna to si dara ju lati ma da bi iya mi ni lati ma bimọ.”

Ni bayii, Fiona, ẹni ọdun mọkandinlọgọta lo n ṣe kokari ẹgbẹ obinrin Bristol Childfree, to si ti n ri apẹẹrẹ pe o ti n sumọ pe ko le bimọ mọ laye ti oloyinbo n pe ni Menopause.

O ni eyi ko ba oun lẹrun pe oun ko ni anfani lati bimọ.

“O tẹ mi lọrun pupọ,” o salaye

Imọtaranikan

Ni bayii, Fiona ri ara rẹ , to si ro pe oun ko ba jẹ obi rere sugbọn oun ko fi bẹ fẹran lati ni ọmọ laye.

Ẹwẹ, o ni pupọ awọn eeyan lo ti bu ẹnu atẹlu lu idi ti oun fi pinnu pe oun ko fẹ ni ọmọ laye.

“Wọn ma sọ fun mi pe ma kabamọ. Ki ni idi ti mo fi wa aye? Ti o ko ba ni ọmọ gẹgẹ bii obinrin.” Fiona salaye.

Fiona ni ọpọ eeyan ti pe oun eeyan to mọ ti ararẹnikan, ti wọn si n bi pe ta ni yoo tọju rẹ to ba darugbo.