You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bola Tinubu and Yemi Osinbajo: Ìjíròrò tó wáyé láàrín Bola Tinubu àti Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo, ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ nìyí
Ni ọjọ Ẹti ni igbakeji aarẹ Yẹmi Oṣinbajo lọ ki aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bsla Ahmed Tinubu ni ile rẹ to wa nilu Abuja.
Ohun ti ọpọ ti n sọ ṣaaju asiko yii ni pe ọrọ gbigbe igba ibo aarẹ ọdun 2023 ti n da họwuhọwu silẹ laarin awọn mejeeji yii.
Amọṣa awọn amugbalẹgbẹ aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC naa ṣalaye pe ojo ti n pa igun Aṣiwaju Bọla Tinubu ati igbakeji aarẹ Yẹmi Ọṣinbajo bọ lọjọ to ti pẹ lati aye alalumọlẹ.
Amugbalẹgbẹ fun Bọla Tinubu lori ọrọ iroyin, Tunde Rahman ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ajọṣepọ awọn mejeeji yii ti n bọ lọjọ pipẹ.
O fi kun pe ipade laarin awọn mejeeji yii kii ṣe ohun to jẹ babara bikoṣe ipade ikini ẹku ọjọ mẹta ti igbakeji aarẹ lọ ki Ahmed Bọla tinubu lẹyin to ti irinajo itọju ara rẹ de.
O fi kun un pe ko soun to jọ ọrọ idibo 2023 ninu ijiroro wọn.
"Gbogbo aye lo ms pe ipade laarin awọn mejeeji nikan leyi, ko si ẹni to lee mọ hulẹhulẹ rẹ, ṣugbọn ohun ti a mọ ni pe ko si ọrọ idibo 2023 ninu ọrọ wọn, ajọṣepọ wọn ti bẹrẹlati ọjọ pipẹ nitori naa ko yẹ ko si babara ninu ipde wọn. Ikini laarin eeyan meji to ti mọ ara wọn lati ọjọ pipẹ wa ni."