Bad road: NLC àtàwọn èèyàn Sango-Ota ti òpópónà Eko sí Abeokuta pa nítorí ọ̀nà tí kò dára

Lẹyin ti wọn ti kọkọ fun ijọba ni ọjọ mọkanlelogun lati ṣe atunṣẹ oju ọna Sango-Ota, ẹgbẹ awọnn oṣiṣẹ, NLC, ti ipinlẹ Ogun, atawọn eeyan agbegbe naa ti gbe ojo ọna marosẹ Eko si Abeokuta ti pa.

Ọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, ọdun yii ni ẹgbẹ NLC ti kọkọ ya bo agbegbe Sango, to wa lopopona Eko si Abeokuta, ti wọn si n halẹ pe awọn yoo ti opopona ọhun ti ijọba ko ba ṣe nnkankan lori ọna ọhun laarin ọjọ mọkanlelogun.

Lẹyin ti gbedeke ti NLC fun ijọba yii pari ni wọn ko awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lọ soju ọna naa, ti wọn si bẹgi dina ọju ọna maroṣe ọhun.

Awọn oṣiṣẹ naa atawọn olugbe agbegbe naa korajọ sibẹ lati ṣe ifẹhonuhan, pẹlu oniruru akọle lọwọ wọn.

Lara awọn nnkan ti wọn kọ si awọn akọle naa ni "Ijọba aninilara yii to gẹ," "Dapo Abiodun, jẹ ka gbadun anfani ijọba awarawa," "Dapo Abiodun, inira yii ti pọ ju," "Gbọ igbe wa, awọn eeyan ipinlẹ Ogun n jiya," "Ba wa tun ọna wa ṣe, ẹtọ wa ni."

Ẹgbẹ oṣiṣẹ naa juwe minisita fun ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe gẹgẹ, babatunde Raji fashola, bii opurọ ati ọta araalu.

NLC ni Fashola ṣabẹwo si ipinlẹ Ogun loṣu diẹ sẹyin, o si ṣeleri pe iṣẹ yoo bẹrẹ loju ọna naa laipẹ ọjọ.

Alaga ẹgbẹ ọhun, Emmanuel Bankole sọ pe awọn eeyan ipinlẹ Ogun ko fẹ ri Fashola soju nitori irọ to pa fun awọn.

O ni "A ti kọkọ wa sibi yii lọjọ mọkanlelogun ṣeyin, a si fun ijọba ni gbedeke pe, bi oju ọna yii ṣe ri ko tẹ wa lọrun, paapaa minisitia fun ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe, ti oun naa si ṣeleri fun wa."

"Ni tootọ, a ri awọn katakata kan atawọn okuta ti wọn ko sibi yii, ṣugbọn ohun ti a n fẹ kọ niyẹn nitori minisita to yọju sibi ti ṣeleri fun wa pe awọn yoo ṣatunṣe ọna naa."

"Ọwọ ijọba ipinlẹ ni a n ri nibi ti a wa lọwọ yii, ijọba apapọ ko le maa pa owo wọle lati ipinlẹ yii ki awa eeyan inu rẹ si maa jiya."

O pari ọrọ rẹ pe awọn yoo tun tẹkọ leti lọ si ọọfisi ajọ FERMA niluu Abeokuta ati ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ ilu lati fi ọrọ ranṣẹ si ilu Abuja pe ohun ti wọn n ṣe ko tẹ awọn lọrun.

Ẹwẹ, awọn eeyan agbegbe naa ṣalayae fun BBC Yoruba pe ohun itiju nla gba ni ọna naa jẹ fun awọn.

Lẹyin naa ni wọn ke si ijọba lati tun oju ọna naa ṣe ki aye le dẹrun fun wọn.