TASUED Protest:

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn akẹkọọ fasiti Tai Solarin to wa nilu Ijebu-Ode nipinlẹ Ogun, tun ti tú sita lati ṣe iwọde tako bi awọn kan ti wọn lo wọ aṣọ ologun ṣe mu awọn akẹẹgbẹ wọn.

Irọlẹ Ọjọbọ ni iroyin jade pe awọn sọja kan ya wọ agbegbe ti awọn akẹkọọ n gbe, ti wọn si ko awọn kan lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ.

Lẹyin iṣẹlẹ yii ni awọn akẹkọọ yooku bọ si oju ọna marosẹ Sagamu si Ore, ti wọn si bẹrẹ si ni ṣe iwọde, eyi to ṣe idiwọ fun lilọ-bibọ ọkọ lojupopo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin sọ pe awọn akẹkọọ kan lo ko ara wọn jọ sinu awọn ọkọ ayọkẹlẹ, ti wọn si n lọ papọ loju popo lati ṣe ajọyọ idanwo aṣekagba ti wọn ṣẹṣẹ pari.

A gbọ pe awọn ṣọja da awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa duro, ti wọn si bẹrẹ si ni yẹ foonu awọn akẹkọọ naa wo.

Eyi lo mu ki awọn akẹkọọ naa pe aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ, Rabiu Sodiq Shina , a.k.a. Reliable Surz, lori foonu lati wa a gba wọn.

Asiko to n da si ọrọ naa ni iroyin sọ pe awọn ṣọja naa to wa lati Bareke Ilase mu oun ati awọn akẹkọọ miran lọ si ahamọ.

Iwe iroyin Daily Post sọ pe Ọga Agba fasiti naa, Ọjọgbọn Wole Banjo, ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ati pe awọn alaṣẹ fasiti naa ti n ṣiṣẹ lati ri i pe ọrọ naa yanju.

Iwọde fọnna soju ni ọgba fasiti TASUED lọjọ Ẹti:

Ṣugbọn ni owurọ oni, ọjọ Ẹti, awọn akẹkọọ naa tun ti bọ si oju ọna marosẹ Sagamu si Ore fun iwọde.

Fidio kan ti BBC wo lori ayelujara Facebook (Facebook live) lasiko ti iwọde naa n waye fihan pe awọn akẹkọọ naa n fẹ lọ si bareke awọn ologun.

Bakan naa ninu ọrọ ti wọn n sọ, wọn ni o di igba ti awọn akẹẹgbẹ awọn ba gba ominira, ti wọn si yọnda awọn dukia wọn ti wọn gba.

Bakan naa la ri pe aṣoju ẹgbẹ akẹkọọ ni Naijiria, Akinwumi Akinsola, ẹkun ti Iwọ Oorun Gusu Naijiria naa darapọ mọ iwọde naa.

Aṣoju ẹgbẹ akẹkọọ naa, sọ pe ara akẹkọọ kan to farapa lasiko ikọlu awọn sọja naa ti n balẹ diẹdiẹ nileewosan.