Abuja kidnap: ''N15m làwọn Fulani ajínigbé kọ́kọ́ bèèrè kí wọ́n tó gba N2.5m ọ́wọ́ wa l'Abuja''
Inu igbo kiji kiji ni a ti gbe miliọnu meji ati abọ naira lọ fawọn Fulani ajinigbe to gbe ọkọ ati ọmọ anti gbe lọ ni ijọba ibilẹ Bwari niluu Abuja.
Kehinde Ibiteye lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba nigba to n sọ ohun ti oju rẹ ri ki wọn to tu awọn ẹbi rẹ silẹ.
Ibiteye ṣalaye pe ọganjo oru ni lawọn ajinigbe pawo ọhun de ti wọn si gbe ọkọ ati ọmọ ẹgbẹ rẹ lọ.
- Darandaran tó bá rúfín dída ẹran nígboro l'Ondo rugi oyin- Akeredolu yarí
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko buwọ́lu òfin máfi ẹranjẹko láàrín ìlú àti VAT
- Kílódé tí Sheikh Gumi fi ṣe àbẹ̀wò sí Igboho nínú gbogbo ìlú tó wà nílẹ̀ Yorùbá?
- Ìjì tó hú igi ńlá ní ìtẹ́ òkú l'Eko ba ibojì òkú 50 jẹ́, àwọn ẹbí sáré lọ w'òkú wọn
- Àwọn jàndùkú agbébọn jí òṣìṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo mẹ́ta lọ
- Wo ìgbésẹ tí Sunday Igboho fẹ́ gbé báyìí lórí àwọn agbẹjọ́rò Cotonou tó ní wón ń gba N4m sí N3m lọ́wọ́ òun
O ni anfaani ti oun ni ni pe oun le sọ ede Hausa tawọn janduku ajinigbe ọhun n sọ.
''Miliọnu mẹẹdọgun ni wọn kọkọ sọ pe awọn maa gba, ṣugbọn mo bẹ wọn lorukọ Ọlọrun ti wọn n sin ti wọn fi gba miliọnu meji ati abọ naira.
Ṣugbọn ibi ẹru ni inu igbo lọdọ awọn ajinigbe naa, ko si ọkunrin to maa de ibẹ ti ẹru ko ni ba a.
Awọn ọlọpaa mọ nipa iṣẹlẹ yii, ṣugbọn wọn ko kọbi ara si ọrọ naa,'' Ibiteye ṣalaye.