Hushpuppi and Daddy Freeze: Ifedayo Olarinde ní Hushpuppi fi ìfẹ́ hàn lásìkò táwọn ìjọ Ọlọ́run gbógun tì òun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Yoruba ni arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ti a ba se lonii, yoo di ọrọ itan to ba di ọla.

Eyi lo mu ki gbajumọ onwoye awujọ ka, Ifedayo Olarinde, ti ọpọ mọ si Daddy Freze se n salaye idi ti ko fi le gbagbe Ramoni Abass, ti ọpọ eeyan mọ si Hushpuppi.

Hushpuppi ni ọlọpaa ilẹ Amẹrika, FBI fi ẹsun kan pe o lu jibiti ori ayelujara ti owo rẹ to miliọnu kan ati ẹgb€run lọna ọgọrun Dọla.

Bakan naa ni Hushpuppi ti n ka awọn eeyan ti wọn dijọ lọwọ ninu ẹsun lilu jibiti naa, ninu eyi ta ti ri ọga ọlọpaa kan nilu Eko, Abba Kyari.

Bakan naa ni iroyin kan tun ni o seese ki Hushpuppi tun darukọ awọn eeyan miran to na ninu owo jibiti naa, paapaa awọn eeyan to ti ba ni ajọsepọ ri lorilẹede Naijiria.

Nigba to wa n fesi lori ọrọ yii, Daddy Freeze, to ti ba Hushpuppi tọwọ bọwọ jẹun lori tabili kan naa salaye pe igba tawsn aye kọ oun silẹ, ni Hushpuppie tẹwọgba oun.

Ninu fidio kan to fi soju opo ayelujara, Daddy Freeze ni awọn ijọ Ọlọrun lo fi oniruuru aisan kan oun lasiko ti Hushpuppi tẹwọgba oun, ti ko si kọ ẹyin si oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Nigba ti mo n fọnrere nipa iwa aidaa ti awọn ijọ Ọlọrun n hu lori gbigba idamẹwa, ni wọn kọju ija si mi, ti mo si dubulẹ aisan lọdun 2017.

Gbogbo ọna ni wọn fi kọlu mi ninu ara, wọn gba awọn ipolowo ọja ti mo n ba wọn se, ti orisun owo to n wọle fun mi si bẹrẹ si poora.

Amọ bi o tilẹ jẹ pe Hushpuppi yii ni wọn fẹsun kan pe o jẹ ogbologbo gbajuẹ, arakunrin yii lo kaanu mi, to si fi ifẹ ati atilẹyin han si mi lasiko isoro ọhun.

To ba wa jẹ pe awọn ijọ Ọlọrun duro ti mi lasiko isoro mi ni, se maa tẹle Hushpuppi lasiko to fi mọto ransẹ pe ki wọn lọ gbe mi wa sibi ti oun wa.

Bi mo ba foju gan ni Hushpuppi bayii, maa sọ fun pe ohun to n se ko dara amọ n ko le wọgile pe o fi ifẹ han si mi lasiko ti awọn ijọ Ọlọrun korira mi.

Bakan ni Daddy Freeze salaye pe lootọ̀ ni oun ko faramọ iwa lilu jibiti tabi gbajuẹ amọ nigba ti oun n ba eeyan kan pin yara sun lasiko ti oun lọ si ilu Dubai, ni Hushpuppi yari pe ki wọn gbe oun wa.

"N ko mọ pe Hushpuppi n lọwọ ninu iwa jibiti amọ bi awọn eeyan se n sọrọ emi pẹlu rẹ, wọn ko se idajọ fun awọn ijọ Ọlọrun to fẹ pa mi.

Ta wa ni maa pe ni esu laarin awọn mejeeji, Hushpuppi ni tabi ijọ Ọlọrun? Ẹ fi ara yin si ipo mi lati se idajọ.

Mo si n kede fun gbogbo aye pe Hushpuppi ko fun mi lowo kankan, boya dọla mẹwa ni tabi marun. Ohun to kan se ni pe o fi ifẹ han si mi.