Hushpuppi Vs Abba Kyari: Igbalode Ramoni tún fi àrídájú ìwé owó tó san sí eèyàn Kyari kan láti GTB àti Zenith hàn FBI

Wo bi ọwọ FBI ṣe tẹ abba Kyari pẹlu iwadii to jinna:

Nigba tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn iṣẹlẹ to wáyé yóò jáde, wọn fẹ̀sùn kan pé Hushpuppi kọ ọrọ atẹjiṣẹ orí fóònù ránṣẹ nọ́mbà kan tí wọ́n wádìí rẹ pé tí Abba Kyari ni.

Kodà, ìwádìí naa fihan pe o gbé ìpè mẹta latodo Hushpuppi tí ọ̀rọ̀ wọn sì ju isẹju méjì lọ.

Lẹ́yìn ìyẹn ni Hushpuppi náà gbà ọ̀rọ̀ atejise láti ọ̀dọ̀ Kyari pé "A ó mú un lónìí tàbí ọ̀la".

Abba Kyari tún kọ pé máa ṣètọ́jú àwọn ikọ mi ti wọn ba ti mú un tán".

Wọn tún fi ẹ̀sùn kàn síwájú sii pé èyí kio ṣe ìgbà kan ṣoṣo tí Abass ṣètò àti san owó fún Abba Kyari.

Ó fi kún un pé ní Ogunjọ oṣù karùn-ún ọdún 2020, Abass fi aridaju àwọn ìwé owó to San ṣọwọ sì Kyari fún owó eemeji (GTBank àti Zenith Bank) han

Eyi to jẹ ti èèyàn kan tí Kyari mọ ni ilu Dubai tí wọn sì ti fi ọwọ òfin mú òun náà.

Àjọ to ń ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ (FBI) lórílẹ̀èdè Amẹrika tí fi ẹ̀sùn kàn pe afurasi ọ̀daràn aji owó nnì, Abass Ramon tí ọ̀pọ̀ mọ si Hushpuppi san iye owo mílíọ̀nù mẹjọ àbí ìṣirò owó dollar $20,600 fún ẹni a fẹ̀sùn kàn, igbakeji Komisonna Ọlọpaa, Abba Kyari.

O ni o san owo yii lati bá a fi òfin mú ẹnikan tó ní o dalẹ oun, Chibuzor Kelly Vincent.

Nínú atejade kan tó wà láti ilé ẹjọ́ California tí wọn kọ ní ọjọ Kejìlá, oṣù kejì fi ẹ̀sùn kàn pe Hushpuppi fi owó náà gbé isẹ mímú Vincent lè Abba Kyari lọwọ ni.

Iroyin ni orúkọ àsùnwọ̀n owó ẹlòmíì ni Kyari fi sọwọ sii to fi gba owó náà.

N8M tán yán-yán ni Abba Kyari gbà lọ́wọ́ Hushpuppi - FBI Amẹríkà

Ọlọ́pàá Amẹ́ríkà, FBI tú àṣírí irẹpọ láàrin Hushpuppi àti Abba Kyari

Àjọ FBI ni nígbà tí Vincent Chibuzo ni kí òun dá sí ọrọ náà, ó ṣàlàyé gbogbo iranwọ to tí ṣe kí wọn leè rí ọ̀daràn náà mú.

Nígbà tó di Ogunjọ oṣù kini ọdún 2020, Kyari fi ọ̀rọ̀ ranse sì Abbas pé "a ti mú ọkùnrin náà. Ó ti wá ní ahamo mi báyìí. Àwòrán rẹ nìyí lẹ́yìn tí a muu lónìí".

Kyari wá fi ìtàn alaye nípa ẹni tí wọn mú àti àwòrán rẹ ranse pelu nọ́mbà Watssap méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ èyí tí Kyari pé èkejì náà ni nomba ikọkọ òun, láti ìgbà náà ni wọn ti ń lo nọ́mbà ikọkọ yìí nìkan fi sọ̀rọ̀ lórí Watssap.

Lẹ́yìn to rí foto Chibuzor, Abass fi ọ̀rọ̀ ranse pé "mo fẹ́ kí ìyá jẹ ilé ayé rẹ daadaa". Kyari sì fèsì pẹlu erin pé "Hahahaha" Abass náà ni "lọ́nà gidi ni sir ó".

Ọrọ ṣaa pọ nínú ìwé kobo lórí bí Hushpuppi àti Abba Kyari ṣe ń fi ọ̀rọ̀ ranse síra wọn tòhun tí owó isẹ loore koore.

Ká má fi ọ̀rọ̀ gùn Abass padà fi ọ̀rọ̀ ranse pé òun ti ń laanu Chibuzor tó ní kí Abba Kyari ati ìko rẹ bá òun fìyà gidi jẹ́ tó sì san owó rẹpẹtẹ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà, òní bí kii se torí Ọlọ́run ni, ìyá to tọ si iru awọn èèyàn bíi tìrẹ nìyẹn.

Ó ní kí wọn jẹ kò lọ sí ilé ìwòsàn fún itoju ara rẹ leyin ọpọlọpọ ijiya tí wón sì gba ọpọlọpọ nkan lọ́wọ́ rẹ gẹgẹ bí Hushpuppi ṣe béèrè tí Kyari sì fèsì pé "bẹẹ ni, kò ní rí rii soju mọ".

Iléeṣẹ Ọlọpaa tí jawe lọ gbele ẹ fún Abba Kyari pẹlu àṣẹ Oga agba àwọn Ọlọpaa, Usman Baba. Bẹẹ si ni wọn ti gbé ìgbìmò kalẹ láti ṣe ìwádìí rẹ.