Ondo kidnap: Fowokemi Ogedengbe, ọmọ Pasitọ Deeper Life tí wọ́n jígbé l'Ondo ní àwọn ajínigbé kò tíì pe àwọn

Awọn ẹbi ati ara Pasitọ ijọ Deeper Life ti wọn jigbe lọ ni ilu Akure, Otamayomi Ogedengbe ni awọn ko i tii gbọ ohun kankan lati ọdọ awọn janduku to ji i gbe lọ.

Iroyin to lo ori ayelujara ni pe awọn ajinigbe ọhun beere fun ọgbọn miliọnu naira lalẹ Ọjọru nigba ti wọn pe ẹbi pasitọ naa.

Iroyin mii tiẹ sọ pe awọn janduku ajinigbe pawo naa sọ pe owo itusilẹ naa ko gbọdọ din ni ọgbọn miliọnu.

Ṣugbọn ọmọbinrin pasitọ naa, Fowokemi Ogedengbe sọ fun BBC Yoruba pe irọ funfun balau ni iroyin tawọn kan n gbe kiri.

Fowokemi ṣalaye pe ẹbi pasitọ Deeper Life ọhun ko ti gbọ lati ọdọ awọn ajinigbe titi di akoko yii.

Ọmọ baba naa ni: ''A ko mọ ibi ti awọn to kọ iroyin pe wọn ti tu u silẹ ti gbó iroyin naa.

Bi emi ṣe rii ka lori ayelujara niyẹn, amọ ko si otitọ kan ninu iroyin naa.

A ko mọ ibi ti baba mi wa bayii nitori awọn ajinigbe naa ko tii pe wa,'' Fowokemi lo ṣalaye bẹẹ.

O rọ awọn eeyan lati maa fi adura ran idile awọn lọwọ wi pe ki awọn janduku ajinigbe naa le fi olori ile wọn silẹ.

Ọmọbinrin Pasitọ Ogedengbe, Fowokẹmi ni inu ipaya ati ibẹru ni awọn wa nitori awọn ajinigbe naa ko tii kan si wọn.

O ni baba oun ni ilera to si ni awọn oogun ti oun lo ni ojoojumọ, amọ lati igba ti wọn ti jigbe lọ yii awọn ko gbọ nkankan.

Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Karun un ni wọn ji pasitọ Godwin Mayomi Ogedengbe lẹyin to pari isin ninu ile ijọsin rẹ ni nkan bi aago mẹsan an alẹ.