Ada Jesus death: Ṣé òtítọ́ ni pé ikú apanilẹ́ẹ̀rín Ada Jesus lọ́wọ́ ayé nínú?

Harrison Gwamnishu to jẹ olutọju adẹrinpoṣonu to jade laye, Mmesoma Mercy Obi ti awọn eeyan mọ si Ada ti kede pe iku to pa a ko lọwọ aye ninu.

O ṣalaye wi pe aisan to ti n ṣe e fun ọjọ pipẹ lo gba ẹmi apanilẹrin naa.

Gwamnishu sọrọ yii laarọ Ọjọbọ lẹyin ti iku Ada Jesus ya awọn eeyan lẹnu ni Ọjọru.

Ki o to di wi pe olutọju Ada Jesus ba a pade, ailera rẹ ti wọ ọ lara gan an debi pe ko le da sọrọ daadaa mọ.

Gwamnishu sọ fun BBC pe iku ati ọdọ Ọlọrun lo pa Ada Jesus.

''Iru iku to pa Ada Jesus to fi ọmọ saye lọ jẹ iru iku to maa ṣaaba pa ọpọ eeyan.

Ada ko ba ti ku to jẹ wi pe wọn tete gbe lọ si ile iwosan ni ṣugbọn aisan naa ti wọ ọ lara pupọ, wọn dokita gan an fidi rẹ mulẹ bẹẹ.

Ara rẹ ti n balẹ diẹ diẹ nigba ti wọn gbe e wa si ibudo itọju awọn to larun kindinrin.

Koda, ọpọ eeyan eeyan lo ti dawo iranwọ fun itọju Ada Jesus ṣugbọn o ṣeni laanu pe o pada ku,'' Gwamnishu ṣalaye.

Gwamnishu sọ pe oun atawọn eeyan kan ti bẹrẹ si ni ba ile iwosan Fortis sọrọ niluu Mumbai lorilẹede India lori ati gbe Ada Jesus lọ fun itọju arun kindinrin.

O ni awọn fẹ ki o gbadun diẹ ki awọn to gbe e lọ si India lati ṣiṣẹ abẹ ipaarọ kindinrin rẹ ki ẹlẹmi to pada gba a.

Gwamnishu fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan kan tiẹ n bẹbẹ lati da owo iranwọ fun itọju Ada Jesus, ṣugbọn gbogbo rẹ ti tan bayii.

Olutọju Ada Jesus sọ pe lootọọ ni adẹrinpoṣonu naa ti ku, ṣugbọn awọn ẹbi rẹ si nilo iranlọwọ awọn eeyan.

Gwamnishu ni ''Ada Jesus fi ọmọ silẹ saye lọ, ọmọ naa si nilo iranwọlọwọ awọn eeyan.

O tun tan imọlẹ si ọrọ kan tawọn eeyan kan n sọ pe ko beere iranwọ owo fun itọju Ada lori ẹrọ ayelujara.

Gwamnishu ni owo kọ ni iṣoro lori ailera Ada Jesus nitori Onimọ ẹrọ Marksman Chinedu Ijiomah ṣetan lati fi miliọnu mẹwaa silẹ fun itọju rẹ.