Fuel scarcity: NNPC ní kò sí ọ̀wọ́n-gógó epo bẹntiró núlùú Abuja

Ko si ohun to jọ pe epo wọn nilu Abuja.

Esi tawọn alasẹ ileesẹ ipọnpo orileede Naijiria,NNPC, n sọ re ni itako iroyin to gbode pe awọn araalu tun ti bẹrẹ si ni to f'epo ni Abuja.

Iroyin to kaakiri ni pe pupọ awọn ileepo ni ko ta epo fawọn ọlọkọ ati pe awọn to n ta gan an nise ni awọn eeyan to nibẹ bi ẹni gba saara lọjọ Isẹgun.

Ninu awọn to ba BBC sọrọ ni ọjọ Aje ni awọn fasiko sofo pupọ nitori tito fun epo.

Awọn kan sọ pe o to wakati mẹjọ tawọn fi to lati le ra epo bẹntiroo.

Ọlọkọ ero takisi ti a baa sọrọ ni awọn ko risẹ se dipo tawọn yoo ti ẹ mu owo lọ ba mọlẹbi.

Ila tito fun epo to gun wọn yi ko sẹyin ọrọ ihalẹ to wa lati ọdọ awọn ẹgbẹ awakọ tanka epo to ni awọn yoo gunle iyansẹlodi lọjọ Aje.

Sugbọn lẹyin igba ti ọga agba ileesẹ NNPC Mele Kyari ba wọn sọrọ, wọn wọgile idasẹsilẹ naa.

Bakan naa ni Kyari kede pe ijọba ko ni fi owo kun owo epo losu to n bọ tii se osu Karun ọdun.

Kyari ni biba ni epo wa nilẹ nitorinaa ko yẹ kawọn eeyan maa fi ibẹrubojo sare ra epo.