Cement price hike: Aṣòfin képe ìjọba láti wá ńkan ṣe sí ọ̀wọ́n-gógó símẹ́ntì ní Nàìjíríà

Ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja ti bẹrẹ igbesẹ lati mu adinku ba ọwọn-gogo simẹnti ikọle lorilẹede Naijiria.

Ile rọ ijọba apapọ lati lati ṣe agbekalẹ ofin ti yoo fun ọpọ lanfaani lati maa ṣe owo simẹnti ki adinku le ba ọwọn-gogo rẹ.

Ile ni ipese ohun amayedẹrun tabi owo iranwọ ti yoo fawọn oniṣowo simẹnti lanfaani lati maa taa fawọn eeyan.

Sẹnẹtọ Ashiru Oyelola Yisa atawọn akẹgbẹ rẹ marun un lo da aba naa eleyi ti gbogbvo ile jiroro le lori.

Sẹnẹtọ Muhammad Enagi Bima; Adelere Adeyemi Oriolowo; Samuel Egwu; Kabiru Gaya ati Michael Nnachi lawọn sẹnẹtọ marun un mii to ṣe agbekalẹ aba ọhun.

Sẹnẹtọ Yisa sọ ninu ọrọ rẹ pe simẹnti wa lara ohun elo ikọle ti orilẹede Naijiria ni yanturu.

'''Bi simẹnti ṣe di N3, 800 lati N2, 600 n jẹ ki iṣẹ ikọle tabi ọna ṣiṣe maa wọlẹ, bakan naa lo n ṣakoba fawọn oṣiṣẹ.

Ileeṣẹ simẹnti mẹta pere, Dangote Cement (60.6%); Lafarge Africa Plc (21.8 %) ati BUA Group (17.6%) lo n ta simẹnti ni Naijiria.

Eyi gan an lo jẹ ki wọn maa gbowo lee lori ni o ṣe wu wọn,'' Sẹnẹtọ Yisa lo sọ bẹẹ.

Sẹnẹtọ Yisa ni ''o yẹ ki o kọ gbogbo wa lominu pe ọwọn-gogo simẹnti pẹlu aiṣowo yoo jẹ ki ayederu ohun elo ikọle pọ, yoo si tun jẹ ki ọpọ iṣẹ di aṣepati.''

Ile fẹnu ko, o si kepe ijọba apapọ lati pese ẹyawo i ko ni gara fawọn oniṣowo simẹnti ni Naijiria ki owo simẹnti le walẹ ki awọn ọmọ Naijiria le maa ra.