Android phone app malware: Ìwádìí fihàn pé àwọn 'App' kan ń ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ fóònù ní Nàìjíríà

Iwadii ijinlẹ kan lorilẹ-ede Naijiria ti fihan pe ọpọlọpọ awọn foonu android lorilẹede Naijiria lo ni awọn eroja ajẹnirun.

Iwadii naa ni ileeṣẹ imọẹrọ nipa foonu ibanisọrọ kan torukọ rẹ n jẹ Upstream gbe sita lẹyin to ṣe ayẹwo ẹgbẹrun lọna irinwo o le marundinlogun idunadura lori foonu ibanisọrọ.

Iwadii naa gba wọn ni oṣu mẹta gbako, eredi rẹ si ni lati ṣiṣọ loju eegun iwa jibiti to waye lasiko igbele ajakalẹ arun coronavirus ni Naijiria, paapaa julọ laarin oṣu kọkanla, ọdun 2020 si oṣu kini, ọdun 2021.

Pupọ awọn eroja ajẹnirun ori foonu wọnyii lo n waye yala nitori atunto eto ori foonu (Changing settings) to lee mu ọpọlọpọ ewu dani debi jiji awọn kọkọrọ makan (Password) atawọn iroyin ara ẹni (personal data) ti a ba fi pamọ sori foonu ẹni.

Iwadii naa fiyeni pe nnkan bii ọrinlelẹẹdẹgbẹta o din mẹrin (576) eroja imọ ẹrọ ori foonu (apps and software programms) lo wa lorilẹ-ede Naijiria bayii.

Ileeṣẹ Upstream gbe iwadii naa jade ni ifọwọsowọpọ pẹlu ẹka iwadii abo igbalode ti wọn n pe ni Secure D.

Wọn ni pupọ awọn eroja yii lo jẹ wi pe ku ori akoto ọja ayelujara Playstore fawọn foonu to n lo Android operating system.

Abajade iwadii naa wa n yọju rẹ sita pe awọn eroja ori foonu marun kan wa ti nnkan ori wọn fẹ suuru bii XOS Launcher, HiOS Launcher, Phoenix Browser, AHA Games ati Cobo Launcher Easily DIY Theme.

Ṣaṣa ni foonu Android ti wọn n ta lorilẹ-ede Naijiria lode oni ti kii si awọn eroja ajẹnirun ori foonu wọn lori wọn.