Oduduwa Nation: Kunle Olajide ní kìí ṣe gbogbo ọmọ Yorùbá ló fara mọ ìyapa Nàíjíríà

Ọkan pataki lara ẹgbẹ igbimọ agbaagba Yoruba, YCE, Dokita Kunle Olajide ti koro oju si bi ọga ileẹkọ girama mẹta se faaye gba ipolongo idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa nileewe wọn.

Olajide ni o yẹ ki ẹnikẹni to fẹ ẹ lọ bá àwọn akẹkọọ sọrọ ninu ọgba ileẹkọ wọn, gba àṣẹ lọwọ ijọba ipinlẹ to n sakoso nipinlẹ naa.

O ni nkan ti awọn Ọga agba ileewe mẹtẹẹta naa ṣe ko boju mu to.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Awọn ọmọ keekeeke ni awọn akẹkọọ naa, ko yẹ ki a ma a gbe ìtọ́ni lori titako ijọba de ọdọ wọn rara. Ko gbọdọ ri bẹ ẹ."

O ni oun faramọ nkan ti ijọba ipinlẹ Osun ṣe fun awọn ọga ileewe naa.

O ṣalaye pe ohun gbogbo ti awọn eeyan to n polongo idasilẹ orilẹ-ede Yoruba ba se gbọdọ ba ofin Naijiria mu, nitori pe abẹ isakoso Naijiria ni wọn si wa.

O ni ẹnikẹni ko ti i le fi ọwọ sọya pe gbogbo ọmọ Yoruba lo fẹ ẹ ya kuro lara Naijiria.

"Awọn ọmọ wa si wa ni ijọba, a ko ṣa le sọ pe wọn kii ṣe ọmọ wa mọ. A ni lati fi suuru ṣe nkan.

Se bi Yemi Osinbajo, tii se ọmọ Yoruba si ni gbakeji aarẹ, se a wa ni kii se ọmọ wa mọ nitori pe a fẹ gba orilẹede Oduduwa."

Dokita Olajide wa rọ awọn eeyan to n polongo fun iyapa orilẹede Naijiria naa lati mase maa tẹ ofin loju nitori ta ba n sunkun, a maa n riran.

Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ tó bá fààyè gba ìpolongo Oduduwa Nation, a fà á lé DSS lọ́wọ́ ni - Ìjọba Osun

Ijọba ipinlẹ Osun ti ṣalaye idi ti wọn fi ni ki awọn adari ileewe girama mẹta lọ rọọkun nile nitori pe wọn jẹ kawọn to n polongo idasilẹ orileede Oduduwa wọ ileewe lai gbaṣẹ.

Kọmisana feto ẹkọ ni ipinlẹ naa, Folorosunso Oladoyin Bamiṣaiye ṣalaye fun BBC Yoruba pe, ṣe lawọn ọga ileẹkọ naa kuna ninu ojuṣe wọn nipa didaabo bo awọn ọmọ to wa ni ikapa wọn.

O ni gẹgẹ bi eleto ẹkọ, awọn ko ni atako si ki awọn eeyan sọ ero ọkan wọn ṣugbọn nigba ti eleyi ba ti n tasẹ agẹrẹ si ẹtọ ati aabo awọn akẹkọọ, o di dandan kawọn gbe igbesẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bamiṣaiye ni ojuṣe awọn oludari ileewe ni lati fi to awọn ọga wọn leti, yala ki awọn to wọ inu ileewe to wọle tabi kete ti wọn ba ti jade nibẹ.

''A gbọ lootọ pe awọn to wọ awọn ileewe wọnyi dira wa ṣugbọn bi wọn ba tiẹ fi tipa mu awọn oludari yii nigba ti wọn wọle, ṣe ko yẹ ki wọn sọ bun wa gbọ nigba ti wọn lọ tan?''

''Ti apa ọga agba ile ẹkọ ko ba ka wọn lati da wọn duro, o le sọ fawọn akẹkọọ pe ki wọn tuka maa lọ si ile wọn. Amọ titi ti a fi kọ lẹta si awọn oludari ileẹkọ yii lọjọ keji, wọn ko sọ nkankan fun wa''

Kọmisana naa fi kun ọrọ rẹ pe, awọn to wa ni Abuja ati Amẹrika lo kọkọ fi fidio bawọn olupolongo yii ti ṣe wọ inu ileewe ranṣẹ si oun.

Nigba ti BBC beere lọwọ rẹ pe, ki ni igbesẹ ti ijọba gbe lati dẹkun iru iṣẹlẹ yii lọjọ iwaju, o ni awọn ti fi iwe ikilọ ranṣẹ sawọn oludari ile ẹkọ to ku pe, bi wọn ba faye gba ẹnikẹni ti ko gbasẹ lati wọ ileewe, wọn yoo foju wina ofin.

'Nibi ọrọ de yii, ipe fun ituka orileede ni wọn n kigbe rẹ, bi adari ileewe kankan ba si faye gba wọn tabi ẹlọmiran wọle lai gba iyọnda, ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni wọn yoo ba lẹjọ''

Ọ̀gá iléèwé mẹ́ta wọ gàù lọ́dọ̀ ìjọba Ọsun torí ìpolongo ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Odùduwà

Ijọba ipinlẹ Osun ti pàṣẹ fun awọn ọga ileewe girama mẹta, lati fi isẹ silẹ fun igba diẹ.

Ẹsun ti ijọba fi kan àwọn eniyan naa ni pe, wọn faaye gba ẹgbẹ kan to n polongo idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, lati ba awọn akẹkọọ wọn sọrọ.

Awọn iwe iroyin abẹle sọ pe ni ibẹrẹ ọsẹ yii, ni awọn eeyan kan lọ si awọn ileewe mẹta ni ilu Irẹsi, nijọba ibilẹ Boluwaduro, nipinlẹ Osun, lati ba awọn akẹkọọ ibẹ sọrọ.

Iroyin sọ pe ẹgbẹ naa sọ fun awọn akẹkọọ naa pe, ki wọn o kọ orilẹ-ede Naijiria silẹ, ki wọn o si beere fun orilẹ-ede Oduduwa.

Sugbọn ṣa, ijọba ipinlẹ Osun ti sọ pe oun ko mọ nipa abẹwo awọn eniyan naa.

Kọmisana fun eto ẹkọ nipinlẹ Osun, Ọgbẹni Folorunsho Bamisayemi sọ ninu atẹjade kan pe, isejọba Gomina Gboyega Oyetola ko mọ nipa abẹwo naa.

Bakan naa lo ni oun ko fun ẹgbẹ naa ni àṣẹ lati ba awọn akẹkọọ ileewe ijọba sọrọ nipa iyapa Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Bamisayemi sọ pe "ijọba ipinlẹ Osun ko fi igba kankan fi ọwọ si ki ẹgbẹ kankan o ba awọn akẹkọọ ileewe rẹ sọrọ nipa ọrọ ti 'a mọ pe o le fa wahala, to si le ba isọkan jẹ ni orilẹ-ede wa".

"Gẹgẹ bi orilẹ-ede Naijiria, a ni igbagbọ ninu àlá rẹ. A si rọ gbogbo ọmọ Naijiria, lati gbadura, ki wọn si ṣiṣẹ́ fun iduro ṣinṣin rẹ.

Ki awọn Ọga ileewe to gba iru ẹgbẹ naa laaye ninu ọgba ileewe wa o mura lati doju kọ ijiya fun nkan ti wọn ṣe."

Bakan naa ninu ọrọ ti ẹ naa, Oludamọran pataki fun Gomina Oyetola lori eto ẹkọ, Ọgbẹni Jamiu Olawumi sọ pe, o ṣeni laanu pe awọn eeyan buruku kan n lọ kaakiri, lati ma gbin èròkerò si ọkan àwọn ọmọde nitori wọn mọ pe wọn ko ti i gbọn daadaa.

O kilọ fun iru awọn ẹgbẹ́ bẹ ẹ lati jina si awọn ileewe nipinlẹ Ọsun.

Yorùbá sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Arewa lórí bó ṣe fẹ́ àtúntò Nàíjíríà àmọ́ tó tako pínpín ipò ààrẹ

Awọn olori ẹya Yoruba kan ti n fesi si ọrọ to jade lati ọdọ awọn ẹgbẹ awọn eeyan apa ariwa Naijiria kan, to ni pe awọn yọnu si atunto Naijiria ṣugbọn awọn ko nifẹ si pinpin ipo aarẹ lẹlẹkunjẹkun, ta mọ si zoning.

Oloye Olusola Ebiseni, gẹgẹ bi iwe iroyin Vanguard ti ṣe sọ, wa lara awọn olori Yoruba to sọ ero ọkan wan nipa ọrọ to jade lati ọdọ awọn olori eeyan apa oke ọya.

Ebiseni ni n ṣe lawọn ọmọ Yoruba dorikodo bii adan, tawọn n wo iṣe ẹyẹ awọn ẹgbẹ ariwa yii nitori wọn ko ṣẹṣẹ maa sọ iru ọrọ bayi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ tirẹ alagba Samuel Adeleye to jẹ aarẹ tẹlẹ ri fun ẹgbẹ agbaagba Yoruba, YCE sọ pe, to ba ṣe pe lootọ lawọn ẹgbẹ eeyan Ariwa fẹ atunto ni, ''wọn yoo ri iyọnu ara ilu''.

Bakan naa ni ọmọwe Yemi Faroumbi, to figba kan jẹ aṣoju Naijiria si Philippines ni, ko si aarẹ kankan to le ṣe aṣeyọri pẹlu bi iwe ofin Naijiria ti ṣe wa yii.

Lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn ẹya Yoruba ti n lewaju ipe lati se atunto Naijiria lọna ti agbara yoo fi dinku lọwọ ijọba apapọ, lọ si ọdọ ijọba ipinlẹ kọọkan.

Pẹlu bẹẹ, ọpọ ti n sọ pe ki awọn ijọba ipinlẹ naa lagbara lori ileeṣẹ ọlọpaa to wa labẹ akoso ijọba apapọ.

Lakotan, ohun tawọn to n sọrọ atunto yii n fẹ, ni ki ijọba apapọ ju ọwọ awọn ojuṣe kọọkan silẹ fun ijọba ipinlẹ, lati le pa owo wọle si bo tilẹ jẹ pe wọn yoo maa san owo ori fun ijọba apapọ.