Oyo kidnap: Ọlọ́pàá, fijilanté àti ọdẹ ìbílẹ̀ bẹ́ sínú igbó, wọn gba obìnrin mẹ́ta lọ́wọ́ ajínigbé

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede itusilẹ obinrin mẹta tawọn ajinigbe pawo gbe lọjọ Aje.

Agbegbe Onipe lopopona Ijebu-ode si Idi-Ayunre ni ijọba ibilẹ Oluyole, ni awọn obinrin naa ti ko sọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso sọ ninu atẹjade to fi sita pe, iwadii awọn ọlọpaa pẹlu iranwọ awọn ọlọdẹ ati fijilante lo jẹ ki awọn obinrin naa ba ominira.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

DSP Osifeso ṣalaye pe awọn ọlọdẹ ati fijilante lo bẹ sinu igbo pẹlu awọn ọlọpaa lati ṣe awari awọn obinrin naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn obinrin ọhun, Temitope Okeowo, Abosede Adebayo ati Bola Ogunrinde ti lọ si ile wọn pada, lẹyin ti wọn ṣayẹwo ara wọn tan.

DSP Osifeso ni iṣẹ ṣi n lọ lati rii pe ọwọ ọlọpaa tẹ awọn agbebọn ajinigbe pawo naa.

Ẹwẹ, kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko ti wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati maa ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa, nipa tita awọn ọlọpaa lolobo lori iwa awọn ọdaran lagbegbe wọn.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Oyo ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kaarẹ nipa didaabo bo awọn eeyan ipinlẹ naa.

Kí ló pa òkú mẹ́jọ tí wọ́n bẹ́ lórí ní Calabar?

Aye fẹlẹ, oriṣiiriṣii iṣẹlẹ lo n ṣẹlẹ ni duniyan.

Lọjọ Iṣẹgun ni iroyin kan jade pe awọn kan ṣadeedee ri oku eeyan mẹjọ ti wọn ti bẹ ori wọn ninu koto ti wọn da wọn sì, lẹnu ọna abawọle silu Calabar, nipinlẹ Cross River.

Agbẹnusọ ajọ ẹṣọ eleto abo NSCDC to ba BBC sọrọ, Solomon Eremi ṣalaye pe, lootọọ ni awọn ri oku eeyan mẹjọ, to ti n jẹra ni abawọlu Calabar.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Eremi ni awọn eeyan kan lo tawọn lolobo pe, awọn n gboorun oku eeyan nibi kan.

O ni lẹyin naa ni ajọ NSCDC ṣe awari ibi ti awọn oku naa ti n run.

Ọgbẹni Eremi ni "a ran àwon ẹṣọ pẹlu ibọn, lati lọ wo ohun to ṣẹlẹ gan an níbẹ.

Oku eeyan mẹjọ ni wọn bá nibẹ, ọkunrin ni meje ninu wọn nigba ti ẹnikan jẹ obinrin.

Ọkan lara wọn si tutu sibẹ."

Agbẹnusọ NSCDC ni awọn ko le sọ pato bi wọn ṣe ku, tabi iru eeyan ti wọn jẹ.

Amọ, o ni ajọ NSCDC n ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ẹka eto ilera ati ayika ijoba ipinlẹ Cross River, lati ko awọn oku naa kuro nibi ti wọn wa nitori wọn ti n jẹra.

Ẹwẹ, awọn ara adugbo ti awọn oku naa wa tiẹ sọ pe, mẹẹdogun ni oku eeyan to wa nibẹ ti wọn si ti ge ori wọn pẹlu.

Awọn agbẹ to n bọ lati oko, ni awọn ara adugbo ni wọn ri awọn oku eeyan naa.

Wọn ni ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ ko jina si ibi t'awọn ọlọpaa ti maa n duro lopopona Calabar si Odukpani.

Awọn ara adugbo ni wọn ti pada ko awọn oku ọhun kuro lagbegbe naa.

Ajínigbe gbé sọ́jà, obìnrin méjì ní Ibadan, wọn tún yìnbon pá ọlọ́pàá l'Abuja

Ko fẹ si ojumọ kan ti yoo mọ lorilẹede Naijiria bayii, ti araalu ko ni gbọ iroyin pe eeyan kan tabi meji tun ti ko si panpẹ awọn aṣebi ati ajinigbe.

Eyi taa tun gbọ laipẹ yii ni eleyi to ṣẹlẹ ni agbegbe Onipe ni Ibadan lọjọ Aje, nibi ti wọn ti ji obinrin mẹta gbe.

Ọkan ninu awọn obinrin yii, Bola Ogunrinde la gbọ pe o jẹ ọmọogun Naijira.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn meji to ku, Temitope Okeowo ati arabinrin Abosede Adebayo jẹ oṣiṣẹ ilera nile iwosan gbogboniṣe Ijebu Igbo.

Gẹgẹ bi iwe iroyin The nation ti wi, awọn ọkunrin meji kan lo fi to awọn ọlọpaa Idi Ayunre leti pe, awọn ajinigbe ti gbe awọn obinrin naa.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adewale Osifesọ sọ pe awọn n gbiyanju pẹlu ikọ fijilante lati ri pe wọn doola awọn arabinrin yii.

Yatọ si iṣẹlẹ ti ipinlẹ Oyo yii, a tun gbọ pe awọn ajinigbe yinbọn pa Inspẹkitọ ọlọpaa kan, Ambi John ni Abuja. nigba to gbiyanju lati doju ija kọ awọn ajinigbe.

Iṣẹlẹ naa to waye ni adugbo Angwan-Zegele-Zuba ni Abuja, la gbọ pe awọn ajinigbe naa pada gbe eeyan meji salọ, ti ọlọpaa kan ati fijilante kan si fara gbọta.

Awọn mejeeji wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

Yusuf Mariam, to jẹ alukoro ọlọpaa ni Abuja naa ti fidi isẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ti n tọ pinpin awọn ajinigbe naa lati le doola awọn to ko si pampẹ wọn.