You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lai Mohammed: Ìgbà márùn ùn ọtọ́ọ̀tọ̀ rèé tí ọ̀rọ̀ mínísítà fétò ìròyìn bí ọmọ Nàìjíríà nínú
Odu ni Minisita feto ibaraalu sọrọ ni Naijiria, Lai Mohammed, kii ṣe aimọ fawọn ọmọ Naijiria.
Yatọ si pe isẹ rẹ gba ki gbogbo ọmọ Naijiria mọ ọ bii ẹni mọ owo, sibẹ, lọpọ igba to ba sọrọ, awọn araalu ki i fẹ́ gbọ ọrọ rẹ.
Yala nitori pe wọn maa n ni ọrọ rẹ jinna sootọ ni tabi pe awọn ko tilẹ nigbagbọ ninu ijọba Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bolanle Ninalowo sọ̀rọ̀ sókè lórí ìdí tó fi kúrò nínú Islam di Krístẹ́nì
- Ohun mẹ́rin tó ṣẹ̀lẹ̀ ní Nàíjíríà nígbà tí Buhari kò sí nílé
- Èèmọ̀ wọ̀lú, Ajínigbé fo ògiri wọnú ààfin, wọ́n jí oríadé gbé l'Ekiti
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Ebi ń pa ajínigbé nínú igbó, wọn ń bèèrè èròjà oúnjẹ́ pẹ̀lú owó ìdáǹdè
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń ta Nàíjíríà lọ́pọ́, ojú yín ti ja lórí iléeṣẹ́ Twitter tó lọ Ghana - Lai Muhammed
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń fẹ́ Oduduwa Nation, ẹ yé tẹ òfin lójú, orílẹ̀èdè Nàíjíríà la ṣì wà - Olajide
- Èèyàn 10 kú, 400 dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n mu ẹlẹ́rindòdò
- Sheikh Muideen Bello, wáàsí rẹ̀, owó ló bá dé - PDP fèsì
- Buhari padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ìsinmi ráńpẹ́ ní London
O ṣeese kẹ ti gbọ pe Lai Muhammed ni awọn akọroyin to n fẹnu tẹnbẹlu Naijiria, lo ṣokunfa bi alaṣẹ Twitter, Jack Dorsey ṣe gbe olu ileeṣẹ rẹ ni Afrika lọ si Ghana dipo Naijiria.
Awuyewuye ọrọ yii ko ti tan nilẹ ṣugbọn ka fi eleyi ṣe iranti fun ara wa ni, nipa awọn igba marun un miran tọrọ Lai Mohammed mu inu bi awọn ọmọ Naijiria.
Diẹ ree ninu wọn:
Lai Mohammed ni ki Big Brother Naija kogba sile tori Covid-19
Lọdun 2020 ileeṣẹ iroyin kan ni Naijiria gbe iroyin jade pe, Minisita Lai Mohammed paṣẹ fun adele adari ajọ to n sakoto eto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria, Armstrong Idachaba.
Wọn ni Muhammed pasẹ fun Idachaba pe ko kọwe si awọn eleto ere idaraya Big Brother Africa, lati kogba sile.
Muhammed, ggẹ bi wn se sọ ni o ṣeeṣe ki awọn eeyan ko arun Covid-19 lori eto naa.
Ọrọ naa ko dun mọ awọn eeyan Naijiria ninu, paapa awọn ọdọ, ti wọn ni Lai Muhammed fẹ gba ohun to n mu inu awọn dun lọwọ awọn ni.
Eto aabo munadoko labẹ aarẹ Buhari
Ni osu kinni lọdun 2021, lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, ni Lai Muhammed kede pe eto aabo munadoko labẹ isejọba Muhammadu Buhari ju tawọn ijba to ti kọja lọ.
Lai sọ pe ka fi ẹgan kun, ka tun yọ tẹgan kuro, eto aabo ni Naijiria munadoko labẹ aarẹ Buhari ju igba ti ijọba ti tẹlẹ, PDP, wa lori oye lọ.
Ayodele Fayose, to jẹ eekan ninu ẹgbẹ PDP wa lara awọn to faraya lori ọrọ yii, ti ọpọ ọmọ Naijiria si kin lẹyin lati gboju agan si Lai Muhammed.
Ko yẹ kawọn ọmọ Naijiria faraya lori ọrọ alekun owo epo
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, naa tun ni Minisita feto iroyin ati asa sọ pe ko yẹ kawọn ọmọ Naijiria bara ajẹ nitori alekun owo eroja epo rọbi.
Lai Mohammed ni ifaraya awọn ọmọ Naijiria lori alekun owo epo kii ṣe oun to yẹ nitori bi owo epo ṣe n lọ soke, naa lo tun n wa silẹ, ko si yẹ ki wọn binu.
Muhammed ni ti owo epo rọbi ba walẹ, o di dandan kawọn araalu san owo kekere lowo epo nitori naa ko yẹ ki wọn maa fa ibinu yọ lori rẹ.
Ero wa ko yipada lori abadofin iṣakoso ẹrọ ayelujara
"Ko si ijọba kankan to ni ifẹ ara ilu lọkan ti yoo faaye gba ki awọn eeyan maa sọrọ ikorira, ki wọn si tun maa pin iroyin eke lori itakun agbaye."
Diẹ ree lara ọrọ ti Minisita sọ nipa abadofin iṣakoso ẹrọ ayelujara tawọn ọmọ Naijiria fi yari mọ lọwọ.
Loṣu Kọkanla ọdun 2019 lo fi ọrọ yii lede, to si tun fi akawe awọn orileede mii lagbaye to n sakoso bi awọn eeyan wọn ṣe n lo ẹrọ ayelujara.
Ninu awọn orileede to darukọ ni Singapore, China, South Korea, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹ̀yin tẹ̀ ń ta Nàíjíríà lọ́pọ́, ojú yín ti ja lórí iléeṣẹ́ Twitter tó lọ Ghana - Lai Muhammed
Minisita feto iroyin ni Naijiria, Alhaji Lai Mohammed ti da si awuyewuye lori bi ileesẹ Twitter ṣe gbe ọọfisi rẹ ni Afrika lọ si Ghana dipo Naijiria.
Lọjọ Aje ni ọga ileeṣẹ Twitter, Jack Dorsey kede pe awọn ti ṣetan lati si ọfisi si ilẹ Afrika, ti olu ileeṣẹ naa yoo si tẹdo si orileede Ghana.
Kete ti o fi ikede yii sita lawọn ọmọ Naijriia ti n sọ ariwisi nipa igbesẹ yii, tawọn kan si ni Naijiria lo yẹ ko gbe ileesẹ naa wa dipo Ghana.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bolanle Ninalowo sọ̀rọ̀ sókè lórí ìdí tó fi kúrò nínú Islam di Krístẹ́nì
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń fẹ́ Oduduwa Nation, ẹ yé tẹ òfin lójú, orílẹ̀èdè Nàíjíríà la ṣì wà - Olajide
- Èèyàn 10 kú, 400 dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n mu ẹlẹ́rindòdò
- Sheikh Muideen Bello, wáàsí rẹ̀, owó ló bá dé - PDP fèsì
- Buhari padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ìsinmi ráńpẹ́ ní London
- Ẹ gbà wá, ọ̀daràn darandaran tún ṣá àgbẹ̀ míì pa, ọ̀rọ̀ yìí yóò di wàhálà láìpẹ́ - Baálẹ̀ Àgbẹ̀ Tapa
- Ẹ wo ọ̀nà táwọn gómìnà Yorùbá yóò gbà láti bọ́ lọ́wọ́ ọ̀dá owó, bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ń lọgun pé ńǹkan le
- Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ tó bá fààyè gba ìpolongo Oduduwa Nation, a fà á lé DSS lọ́wọ́ ni - Ìjọba Osun
- Ẹ wo àwọn àdúgbò mẹ́wàá tó gbajúmọ̀ jùlọ ní ìlú Eko
- Àjọ̀dún òkú rèé níbi tí alààyè ti ń tọrọ owó, ọmọ àti ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ ẹ̀mí àìrí
Alaye tawọn ọmọ Naijiria fi kin ọrọ wọn lẹyin ni pe, Naijiria tobi ju Ghana lọ pẹlu awọn idi miran.
Lai Mohammed naa wa salaye idi ti ọrọ naa fi ri bẹẹ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ l‘Ọjọbọ.
O ni ohun to yẹ ni pe ki Twitter gbe olu ileeṣẹ rẹ ni Afrika wa si Naijiria ''nitori nkan bi eeyan miliọnu marundinlọgbọn lo n lo Twitter ni Naijiria, ti
wọn ko si ju miliọnu mẹjọ lọ ni Ghana''
''Lai si iye meji, kii ṣe nitori ọrọ aje lo fi tori rẹ gbe igbesẹ yi''
Lai Muhammed ni Twitter lẹtọ lati gbe olu ileeṣẹ rẹ lọ si ibikibi to ba wu u.
Minisita wa fi ọrọ kun eleyi ti o sọ pe "Mo lero pe eleyi yoo jẹ ẹkọ fawọn ọmọ Naijiria.''
Lai ni ''Nkan ti oju eeyan maa n ri ree, ti o ba ta orileede rẹ lọpọ nitori ọpọlọpọ igba lawọn eeyan ma n sọ asọdun lori ipenija to n koju Naijiria.''
O tẹsiwaju pe ''ko si igba teleyi foju han bi asiko iwọde ENDSARS nibi tawọn akọroyin ti n jijadu laarin ara wọn lori ẹni ti yoo ṣapejuwe Naijiria
gẹgẹ bi ọrun apaadi ti awọn eeyan ko gbọdọ wa sibẹ.''
O ni oun dupẹ lọdọ Ọlọrun pe orileede Amẹrika fọ Naijiria mọ pe ko si eeyan kankan to ku ninu iṣẹlẹ Lekki Toll Gate.
Minisita naa pari ọrọ rẹ pẹlu amọran sawọn ọmọ Naijiria lati nifẹ ilẹ wọn lọkan.
O ni ''bi o ba ba ile ara rẹ jẹ, nibo lo ku ti wa a gbe?''
Twitter gbé olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Áfíríkà lọ Ghana, ọmọ Nàíjíríà yarí
Ilé iṣẹ́ Twitter tó fi ilẹ̀ ilẹ̀ Amerika ṣe ibùdó ti yàn orílẹ̀ -èdè Ghana gẹ́gẹ́ ofíisì rẹ̀ túntun ni afirika, sùgbọ́n ọpọ ọmọ Naijiria lo n beere pe kí ló mú wọn yan Ghana láàyò gan?
Lọ́jọ́ Ajé òṣẹ̀ yìí ní Jack Dorsey fi léde lórí twitter pé, "Twitter ti balẹ̀ bàgẹ sí ilẹ̀ adúláwọ̀. Ghana ẹ seun o àti @NAkufoAddo".
Eyi si lo dabi ni pe ileesẹ Twiitter fi n kéde agbekalẹ ọọfisi rẹ akọkọ ni Afirika.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- Arapaja jáwé olúborí nínú ìdìbò alága ẹgbẹ́ ìwọ òòrùn gúúsù
- Ọlọ́pàá yìnbọn lu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ nílùú Eko, wàhálà dé
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ lágbo tíátà Yoruba, àgbà òṣèré míì tún jáde láyé
- Makinde fàgbà han Fayose, Arapaja fi ẹyin alátako janlẹ̀ láti dì alága PDP ní SW
- Ọmọ yẹrí ẹ, èpè ń bọ̀! Kí ló dé tí Foluke Daramola bu èpè jólẹ̀ lórí ayélujára?
- N kò ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Boko Haram àti Al-Qaeda, ẹbu ìròyìn ló jáde síta - Mínísítà
Kí ọ̀gà àgbà pátápátá fun ileesẹ Twitter tó le kọ èyí sí ojú òpó twitter rẹ̀, tó sì tún ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀èdè Ghana ni ọdún 2019, eyi fi han pé ìjọba Ghana wà lẹ́yìn ilé iṣẹ́ náà gbáágbágbá.
Àsìkò yìí bákan náà tó sàbẹ̀wò sí Ghana ni Dorsey ń ṣe àbẹ̀wò káàkiri awọn orílẹ̀-èdè to wa nilẹ̀ Afrika, bákan náà ló sì sọ pé, òun fẹ wá gbé ilẹ̀ adúiláwọ̀ fún oṣù mẹ́ta sí mẹ́fà.
Amọ o ni òun kò ti mọ ibi ti òun yóò gbé ni Afrika. Sùgbọ́n ó jọ bi ẹni pé gbogbo ètò ló ti tò lati tẹdo si Ghana, ni ọ̀gá àgbà twitter ṣe kọ sórí twitter fúnra rẹ̀.
Ààfàní rèé fún Dorsey láti gbé, ki o sí kópa nínú si agbega ètò ìmọ̀ ẹ̀rọ ni ilẹ̀ adúláwọ̀, kó jẹ́ pé Ghana náà ló wà, eyi yóò jẹ́ ìwúrí fún ọ̀pọ̀ ọmọ aláwọ̀ dúdú nilẹ̀ Afíríkà.
Abẹ̀wọ sojú òpó Twitter fi han pé ààyè mẹ́sàn ló ṣí sílẹ̀ fún ìṣẹ́ níbẹ̀ Sàbẹ̀wò sí ojú òpó wọ́n níbí
Wayi o, ìdùnnú súbú lu ayọ ni ìròyìn náà fún àwọn olùgbé Ghana, tó fí mọ ààrẹ Ilẹ̀ Ghana, Nana Akufo-Addo, tó sàkàwé ìgbésẹ̀ náà bíi èyí tó dára, sùgbọ́n ọ̀rọ̀ ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Awọn ọmọ Naijiria fariga:
Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe n gbarata pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ọọ́fíísì túntun ileesẹ Twitter naa tọ́ sí, ni àwọn míràn gbà pé ijọbaNàìjíríà àti ètò ààbò tó mẹ́hẹ, kò lé jẹ́ kí irú ilé iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ wá tẹ̀dó sí Nàìjíríà.
Ó kọ́ pé, " Ìfọkànbalẹ̀ tí a ni láti gbé ilé iṣẹ́ wa sí Ghana jẹ́ ìròyìn ayọ, ìjọba Ghana fi tayọ̀tayọ̀ gba ìkéde náà, ó sì ni ìbáṣepọ̀ wọn yóò dán mọ́rán.
Kíní ìdí ti Twitter fi yan Ghana Láàyò?
Ó lè jẹ́ pé nítórí Ghan a máa gbárùkù tí òwò
Gẹ́gẹ́ bi ìwádìí Bánkì àgbáyé kan tó jáde ni ọdún 2019, ipò 118 ní Ghana wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tí o rọrun láti ṣe òwò lẹ́gbẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó wà nípò 131.
Ìtùmọ̀ èyí ni pé, ẹni tó jẹ́ ipò àkọ́kọ́ ni òwò dùn ṣe jù níbẹ̀, ìpò tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà túmọ̀ sí pé kò rọ̀rùn rárá lati se owo lorilẹede rẹ.
Sùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá yìí ṣe sọ, òun yàn orílẹ̀-èdè Ghana nítori pé ètò ìjọba àwa arawa ń rú gọ̀gọ̀ níbẹ̀.
Bákan náà lo ni wọ́n faramọ́ òmìnirà láti sọ èrò ọkàn ẹni lórí ayélujára, pàápàá jùlọ lórí ayélujára èyí tí twitter ń pè fún.
Bákan náà ni twitter tún sọ àwọn ìdí míràn tí wọ́n fi yan Ghana láàyò bí i eto ajọsepọ okoowo lai ni owo ori ọja ninu, taa mọ si "African Continental Free Trade Zone "
Ilé iṣẹ́ twitter ni ẹka ilé iṣẹ́ rẹ méjìlélọ́gbọ̀n ni orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlógún.