You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mary Daniel: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan náà yóò wà ní ìkáwọ́ òun títí tí yóò fi bẹ̀rẹ̀ òwò
Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe oun yoo bojuto bi Mary Daniel, obinrin to n ta omi ninu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ lagbegbe Oshodi, yoo ṣe maa gbe igbe aye to dara lati akoko yii lọ.Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ bẹrẹ si n fi owo ṣọwọ si obinrin naa, ni kete ti aworan rẹ fa ori ayelujara ya.Anu rẹ ṣe ọpọ ọmọ Naijria lasiko to ba awọn akọroyin sọrọ, lori ohun to ti la kọja lati igba to ti padanu ẹsẹ rẹ kan ninu ijamba ọkọ lọdun 2006.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Arapaja jáwé olúborí nínú ìdìbò alága ẹgbẹ́ ìwọ òòrùn gúúsù
- Ọlọ́pàá yìnbọn lu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ nílùú Eko, wàhálà dé
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ lágbo tíátà Yoruba, àgbà òṣèré míì tún jáde láyé
- Makinde fàgbà han Fayose, Arapaja fi ẹyin alátako janlẹ̀ láti dì alága PDP ní SW
- Ọmọ yẹrí ẹ, èpè ń bọ̀! Kí ló dé tí Foluke Daramola bu èpè jólẹ̀ lórí ayélujára?
- N kò ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Boko Haram àti Al-Qaeda, ẹbu ìròyìn ló jáde síta - Mínísítà
Lẹyin ti ọrọ Mary jade sigboro ni olubadamọran Pataki si gomina ipinlẹ Eko lori ọrọ araalu, Aderemi Adebowale sọrọ sita nipa obinrin naa.
O ni ijọba ipinlẹ Eko ti mu arabinrin ọhun sọdọ, titi ti wọn yoo fi ṣeto bi awọn yoo ṣe gba ile fun, ati bi wọn yoo ṣe tọ sọna lori owo ti yoo maa ṣe.
Adebowale, lasiko to n ba iwe iroyin Punch sọrọ ni "mo gbọ nipa Mary lọjọ Aje nigba ti awọn oloṣelu meji kan mu wa si ọdọ mi pẹlu kaadi ATM rẹ.
Wọn ni o yẹ ki a daabo bo nitori iye owo to n wọle sinu apo rẹ ni banki.""Mo ti ke si kọmiṣọna to n ri si ọrọ awọn ọdọ, a o fi Mary pamọ si ile kan lagbegbe Ikorodu fun nnkan bii ọsẹ kan, titi ti a o fi wa ile fun."Adebowale pari ọrọ rẹ pe, oun yoo maa ṣe itọju ati alamọna rẹ, oun yoo si ri daju pe o di olugbe ilu Eko tootọ.
Lara awọn eeyan to ti fi owo ṣọwọ si Mary ni oludije sipo gomina nipinle Imo tẹlẹ, Uche Nwosu, to fun ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira.
Awọn ọrẹ Nwosu naa tun ṣeleri iye owo yii bakan naa gẹgẹ bii ẹbun fun Mary Daniel.
Òjò owó ń rọ̀ fún abilékọ ẹlẹ́sẹ̀ kan tó n ta pure water lójú pópó
Saaju lati ti mu iroyin wa fun yin pe nkan bii ọjọ melo kan sẹyin ni aworan obinrin to n ta omi inu ọra pẹlu ẹsẹ kan fa ori ayelujara ya, ti ọpọ si n kaanu rẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ fun awọn akọrọyin niluu Eko, obinrin ọhun ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Mary Daniel sọ pe, iṣẹ agbẹjọro lo wu oun lati ṣe lati kekere, ṣugbọn ijamba ọkọ lo sọ oun di ẹlẹsẹ kan.
Mary ṣalaye pe oun nikan lo moribọ ninu gbogbo awọn to wa ninu ọkọ ti ijamba ọhun ti ṣẹlẹ lọdun 2006.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
- Ẹ wo ìdí tí omije fi bọ́ lójú Pasuma níbi ìgbéyàwó ọmọ rẹ̀ obìnrin
- Ikọ̀ aláàbò Ebube Agu bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Igbo, tó túmọ̀ sí Amotekun
- Agbára ahọ́n ta fi n pe ara wa ní olóríire ló jẹ́ ká gba ẹ̀bùn ilé - Olorì Aláàfin méjì
- Ẹ̀tanú ní kó jẹ kí wọ́n gbé ipò ààrẹ fún MKO Abiola - Obasanjo
- Alaafin kọ́lé tuntun fún ọ̀kan lára Olorì rẹ̀ ní Ibadan, ariwo sọ
- Davido, Pasuma àti Yinka Ayefele dábírà lópin ọ̀sẹ̀, aráyé múgbe bọnu
- Yorùbá sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Arewa lórí bó ṣe fẹ́ àtúntò Nàíjíríà àmọ́ tó tako pínpín ipò ààrẹ
O ni "ọdun 2006 ni mo ni ijamba ọkọ nigba ti emi atawọn obi mi n rinrinajo lọ si abule wa, ọmọ ọdun mẹwaa ni mi lasiko naa, emi nikan ni mo ru ijamba ọkọ naa la nitori awọn eeyan marundinlogun to ku ba a lọ."
Mary tẹsiwaju pe, awọn eeyan ke si iya-iya oun lori aago lẹyin ijamba ọkọ ọhun, ṣugbọn ki wọn to foju ganni ara wọn, wọn ti ge ẹsẹ oun kan, bii bẹ kọ, o ṣeeṣe ki oun naa ba iṣẹlẹ naa lọ.
Lẹyin ọdun mẹwaa, ni Mary tẹkọ leti lọ si iluu Onitsha, nibi to ti bẹrẹ si n ta omi inu ọra ti ọpọ mọ si "pure water" pẹlu ẹsẹ kan.
Ilu Onitsha yii lo wa ti iya-iya rẹ naa ti ke si pe wọn ti ba ri ọkọ, ṣugbọn ere ifẹ oun ati ọkọ naa ko lọ titi nitori ọkunrin ọhun kọ lati tọju rẹ, koda ọkunrin naa tun lu ni jibiti owo pẹlu.
Nigba to n ṣalaye bi ere ifẹ wọn ṣe dopin, o ni "lẹyin ti mo loyun tan ni ọkọ mi yi iwa pada, emi ni mo n da nikan gbọ bukata bi mo ṣe n jẹun pẹlu oyun inu mi."
Ko pẹ si asiko naa ni mo tẹkọ leti lọ si ilu Asaba, nibi ti mo ti n ta omi inu ọra pẹlu ẹsẹ kan yii naa, mo gbiyanju lati gba ile, lẹyin naa ni mo ke si ọkọ mi lati maa gbe pẹlu mi ko to di pe mo bi ọmọ.
Ko pẹ si asiko yii ni mo ri oloju anu kan to fi N500,000 ta mi lọrẹ, ṣugbọn bi ọkọ mi ṣe ko firi owo naa, lo ko ẹrọ ibaraẹnisọrọ mi ati kaadi ATM mi, to si gba gbogbo owo naa ku ẹgbẹrun meji pere."
Mary sọ pe oun ko tii foju gan ni ọkunrin naa lati igba to ti gbe oun lowo salọ.
Akanda ẹda naa pari ọrọ rẹ pe, yoo wu oun lati fi iṣẹ omi inu ọra tita silẹ ti oun ba ri oluranlọwọ, ati pe iṣẹ aranṣọ lo wu oun lati ṣe niwọn igba to jẹ pe oun ko nilo ẹsẹ meji lati ranṣọ.
Lẹyin ti aworan abarapa naa gbajumọ tan lori ayelujara, ni awọn ẹlẹyinju anu kan bẹrẹ si n ko owo jọ fun Mary lati fi seranwọ fun.
Lara awọn to fi owo ṣeranlọwọ fun obinrin ọhun ni akọwe ijọba ipinlẹ Imo tẹlẹ, Ugwumba Uche Nwosu, to fun ni sọwedowo miliọnu kan naira.
Titi di akoko ti a nko iroyin yii jọ, awọn ẹlẹyinju anu kan si n gbiyanju lati ṣe iranlọwọ fun