June 12 Annulment: Obasanjọ ní àwọn tí kò gbé ìjọba lè MKO lọ́wọ́ ṣé bẹ́ẹ̀ nítorí ẹtáànú ní

Aarẹ orileede Naijiria tẹlẹri Olusegun Obasanjo ti sọrọ lori bi wọn se wọgile ibo aarẹ ti Moshood Kashimawo Olawale Abiola jawe olubori ninu rẹ, loṣu Kẹfa ọdun 1993.

Obasanjo woye bẹẹ lasiko ayẹyẹ ifami ẹyẹ dani lọla to waye ni Abeokuta labẹ asia ẹgbẹ awọn ọmọ ẹgba nipinlẹ Ogun.

Aarẹ ana ni Naijiria naa, ti wọn dijọ da lọla pẹlu MKO Abiola salaye pe, ẹtaanu ni ko jẹ ki wọn gbe ipo naa fun Abiola.

O ni bi bẹẹ kọ, ko ba jẹ pe ọmọ ẹgba mẹta ni yoo di ipo aarẹ mu ninu akọsilẹ Naijiria .

Nibi ayẹyẹ ifamiẹyẹ danilọla naa ni Obasanjo ti wa ṣapejuwe MKO gẹgẹ bi akẹẹgbẹ rẹ nile iwe girama.

Abiola ati Obasanjo jijọ lọ si ile ẹkọ girama Baptist Boys High School nilu Abeokuta nigba ewe wọn.

Yatọ si Obasanjo, Ernest Shonekan to jẹ olori ijọba fidihẹ ni Naijiria naa de ipo aarẹ, bo tilẹ jẹ pe fun igba diẹ lo fi lo ipo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Mo fẹ dupẹ lọwọ ẹgbẹ Abeokuta Club fun ọla ti wọn fi da mi lọla yii ati iyi ti wọn ra fun akẹgbẹ mii, MKO Abiola.''

''Kabiyesi Alake sọrọ nipa rẹ, ṣẹ si mọ pe bi eeyan ba gba ife lẹẹmẹta, o di ti onitọun niyẹn. Bi kii ba ṣe ẹtaanu, Abeokuta ko ba ti ni aarẹ lẹẹmẹẹta bayi''

Ọrọ ti Obasanjo sọ yii ṣebi ẹni tako oju tawọn eeyan fi n wo ibaṣepọ to wa laarin oun ati MKO nigba aye rẹ, paapa awọn mọlẹbi MKO to ri Obasanjo gẹgẹ bi ẹni ti ko fẹran MKO.

Lọpọ igba ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu awọn akọroyin, lawọn mọlẹbi oloogbe ti ni Obasanjo ko gbiyanju to lati bu iyi fun Abiola lasiko to wa lori oye gẹgẹ bi aarẹ.

Ọrọ yii tun jẹyọ bi ere bi ere lasiko ti ijọba Muhammadu Buhari yẹ Abiola si, nipa fifi orukọ papa iṣere nla Abuja peri rẹ, ti wọn si tun sọ June 12 ni ayajọ oṣelu awarawa ni Naijiria nitori rẹ.