Nigeria Democracy: Buhari buwọ́lu àbádòfin 'June 12' gẹ́gẹ́ bí àyájọ́ ọjọ́ ìjọba àwarawa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Lẹyin ọ rẹyin, ''June 12'' pada ayajọ ọjọ isinmi ijọba awarawa lorilẹede Naijiria lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari buwọ lu abadofin naa.

Oluranlọwọ aarẹ lori ọrọ ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lo fọrọ naa lede.

Ohun ti igbesẹ yii tumọ si ni pe lati akoko yii lọ, ko ni si isinmi lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un mọ to jẹ ayajọ ọjọ ijọba awarawa tẹlẹ.

Ọjọ kọkandinlọgbọn yoo kan jẹ ọjọ ifilọlẹ ati iburawọle ijọba tuntun lorilẹede Naijiria.

Igbesẹ aarẹ lati buwọlu ''June 12'' waye ni ọjọ meji peri si ọjọ kejila oṣu kẹfa tii ṣe Ọjọru.

Laipẹ yii ni ile igbimọ aṣofin agba mejeeji l'Abuja fi abadofin naa ranṣẹ si Aarẹ Buhari.