You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
M.K.O: Igi ni Abiọla ṣẹ́ tà láti tọ́ àwọn àbúrò rẹ̀
- A bí Moshood Olawale Abiola Kashimawo ni oṣù kẹ̀jọ, ọdún 1937, ó jẹ́ ọmọ bíbí ilú Abẹokuta, ni ìpínlẹ̀ Ogun
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ìtàn ìgbé ayé olóyè MKO Abiọla
- Ó kú ní ọja kèje osù keje, ọdún 1998 lẹ́yìn ìdìbò sípò ààrẹ ti gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé òun ló jáwé olúbori
- O díje dupò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dun 1993 tí ijọba Babangida sì fígilé, èsì ìdìbò náà tí wọn ò sì kéde rẹ̀ títí di òní yìí nítorí wọn ni àwọn èrí pé èrú wá nínú ìdìbò náà.
- Ní ọdún 1994, Abiọla kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúbori nibi ìdìbò ààrẹ fún Nàìjíríà ti ọdún 1993 ní ìlú Ẹ̀pẹ́tẹ̀dó ní ìpínlẹ̀ Èkó, lẹ́yìn tí Abíọ̀lá ṣe èyí tan ní wọn bẹ̀rẹ̀ síí wáa kiri pe ó lu òfin ìjọba, wọn gbé e sì tì mọ́lé lábẹ àṣẹ ààrẹ Sani Abacha nipa lilo ólọ́pàá tó tó igba gbé e lọ sí àtìmọ́lé.
- Èyí dá wàhálà oṣèlú sílẹ̀, Lẹyin ti Babangida gbe ijọba fìdíhẹẹ́ fún Oloye Ernest Ṣonẹkan ki ọ̀gágun Sani Abacha to fipa gbà ìjọba lọdún náà
- Wọ́n fi Abiola sí ẹ̀wọn fún ọdún mẹ́rin, tí òun níkan sì dá wà pẹ̀lú Bíbélì, kùránì àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rìnlá.
- Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ní gbájúgbajà oníwàásù Nàìjírìá kan tí sọ tẹ́lẹ̀ pé kí Abíola má díje fún ìdìbò tẹ́lẹ̀.
- Abiola bẹ̀rẹ̀ oṣẹ̀lù láti ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún nígbà tí ó wọ ẹgbẹ́ NCNC ní ọdún 1979,
- Abiola kú ni ọjọ́ keje, oṣu keje, ọdún 1998 ní ọjọ́ ti o yẹ kí ó kúrò lẹ́wọ̀n lẹ̀yìn ikú Abacha ti àwọn ènìyàn sì ní ìgbàgbọ́ pé ejò lọ́wọ́ nínú lórí ọ̀rọ̀ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyẹ̀wò òkú tí wọn ṣé fún Abiola sọ pé àmúwá Ọlọ́run, bẹẹ olórí aláàbò ìjọba Abacha, Al-Mustapha sọ pe òun lọ́wọ́ nínú ikú Abiola.
- M.K.O Abiola lo àkọlé 'Ìrètí fún ìpolongo ìdìbò lọ́dún 1993 èyí ti ààrẹ àna orílẹ̀-èdè Amẹríkà, Barrack Obama, náà mú lò ní ọdún 2008.
- M.K.O Abiọla kú fún June 12 sùgbọn kìí ṣe òun nikan ló kú fún, ológùn Sani Abacha náà kú ikú tó yani lẹ́nu ni June 8, 1998.
- Wọn n ranti Àyésí Oloye Abiola ní Naàìjíríà àtí ni gbogbo àgbaye tí àwọn ìpínlẹ̀ Eko àti Ogun sì máa ń yà sọtọ fún ọjọ́ ìsinmi.
- Ọpọlọpo ẹmi lo sọnu sori ọrọ Abiọla ati June 12 bii ti aya rẹ Kudiart Abiọla.
- Ìjọba àpapọ Naijiria ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde June 12 gẹgẹ bii ọjọ́ ayẹyẹ ìjọ̀ba àwa-ara-wa ni Naijiria bẹrẹ lati ọdun to m bọ.
- Ó jẹ́ bàbá fún ọmọ tó tó ogójì pẹ̀lú ìyàwó mẹrin.
- Abiọla ni ọmọ kẹtalélogun fún bàbá rẹ̀.
- Òwò igi ṣiṣẹta ni Abiola fi bẹ̀rẹ̀, tí ó sì fi ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ láti fi tọ́ àwọn àbúrò rẹ̀.
- Ó jẹ olùdárí iwe ìròyìn Trumpeter ti Obasanjọ sì jẹ́ igbákejì rẹ̀, ó ti pèsè ìrànwọ́ ọgọfà mílíọ̀nù náírà fún àwọn ilé ìwé gíga Nàìjíríà, bákàn náà ní àwọn ìrànwọ́ rẹ̀ ti yorí sí kíkọ̀ ilé ìwé mẹ́tàlélọ́gọ́ta, mọ́sálásí àti sọ́ọ̀sì mọ́kànlélọ́gọ́fa, yàrá ìkàwé mọkanlelogoji, àkànsé omí mọ́kànlélógún nati bẹẹ bẹẹ lọ ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlélógún ní Nàíjíríà.
- Abiola gbe ìyàwó àkọ́kọ́ rẹ, Simibiat Atinuke Shoaga ní 1960, Kudirat Olayinka Adeyemi ní 1973, Adebisi Olawunmi Oshin ní 1974, and Doyinsola (Doyin) Abiola Aboaba ní 1981.