June 12: Ilé Aṣòfin rọ INEC ko kéde èsì ìbo àarẹ 1993

Ilé Ìgbìmọ Aṣòfin Àgbà ti ké pe àjọ elétò ìdìbo Naijiria (INEC) láti kéde èsì ìbo ti àarẹ 1993 ti gbogbo eniyan gba pe olóògbé MKO Abiola ti jáwé olú borì.

Àwọn aṣòfin náà, sọ̀rọ̀ yí ní Ọjọ́bọ lákókò ìjókòó lẹ́yìn ọjọ́ tí Aare Muhammadu Buhari kéde pé òun ti yí àyájọ́ ọjọ́ ìjọba tiwantiwa padà láti May 29 sí June 12 láti fi buyì kún Abiola.