You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
June 12: Ère tuntun tí Ìpínlẹ̀ Eko mọ fún MKO Abiola
Gómínà Ìpínlẹ̀ Eko, Akinwunmi Ambode ti ṣí ère olóògbé Moshood Abiola tuntun, èyí tíí se ára àwọn ètò tí wọ́n fi ṣe ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ June 12.
Eré náà ló wà ní ọgbà ìgbafẹ́ MKO Abiola ní Alápẹ̀rẹ̀, Ketu.
Ambode ní ó jẹ́ dandan láti yẹ́ Abiola sí nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fun gbogbo ọmọ Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gomina Ambọde ní oun ri pe, ó yẹ kí ìjọba ṣe ère to ga ju ti tẹ́lẹ̀ lọ láti yẹ́ẹ̀ Abiola sí.
Ere náà lo jẹ́ ẹsẹ bàtà mẹ́tadínlógójì. Ọdún kan si ló gba àwọn tó ṣe ère nàá láti pari rẹ̀.
Ambode, tí Kọmíṣọ́nà fun ètò ìròyìn, Kehinde Bamigbẹ́tàn ṣojú rẹ̀, níbi àyájọ ọjọ́ akọsilẹ ìsẹ̀lẹ̀ tó ti kọjá lọ, èyí tó wáyé ní àdúgbò Ìkeja, sọ pé, ó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ gbe fọ́nrán ohùn àti àwòrán ìgbà ìkẹ̀yìn Abiola síta, kí gbogbo ayé leè ríi.