You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wasiu Alabi Pasuma: Kwam1 ṣeré níbi ìgbeyàwó ọmọ ọ̀gá ńlá Fuji, ló bá bú sẹ́kún
Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn wo o pe ki lo ṣẹlẹ si gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Alabi, ti gbogbo eniyan mọ si Pasuma, ti omije fi n bọ loju rẹ ni ọjọ igbeyawo ọmọ rẹ obinrin.
Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kẹrin ni gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde ṣe Nikkah fún ọmọ rẹ obinrin, Barakat.
Pasuma ti o ti kọrin kaakiri agbaye, paapaa ni Naijiria ti awọn eniyan si gba tirẹ, lo barajẹ pẹlu omije loju ni ọjọ igbeyawo ọmọ rẹ naa.
Awọn ọ̀rẹ rẹ lo ṣugba rẹ ni oju agbo nibi to ti bu si ẹkun, ti wọn si gbe e mọra, amọ niṣe ni omije n bọ ni oju rẹ poroporo.
Wasiu Ayinde, K1 to wa kọrin nibẹ, tawọn ọrẹ rẹ to di mọ si parọwa fun un pe ko dakẹ ẹkun sisun.
Ki ni idi ti Pasuma fi n sukun?
Wasiu Alabi ni ẹkun ayọ ni oun sun ni ibi igbeyawo ọmọ oun obinrin, kii ṣe ẹkun ibanujẹ.
Pasuma ni ọpọlọpọ ni ko mọ iru ipọnju ti oun ti la kọja ko to di wi pe oun di ẹni to n ṣe igbeyawo fun ọmọbinrin oun keji.
''Ọpọlọpọ awọn eniyan ri ogo naa ni oni, amọ wọn ko mọ itan to gbe mi de ibi ti mo wa yii.''
''Mo dupẹ ni ọwọ Ọlọrun to jẹ ki n ri ọjọ igbeyawo ọmọ mi, inu mi dun gidigidi''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Alaafin kọ́lé tuntun fún ọ̀kan lára Olorì rẹ̀ ní Ibadan, ariwo sọ
- Ìsìn àrà ọ̀tọ̀ wáyé níjọ Canterbury Cathedral láti yẹ́ Ọmọọba Phillip sí
- Yorùbá sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Arewa lórí bó ṣe fẹ́ àtúntò Nàíjíríà àmọ́ tó tako pínpín ipò ààrẹ
- Jàndùkú pa ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta l‘Eko bó ṣe kù díẹ̀ kóun àti ẹbí rẹ̀ lọ tẹ̀dó sí Canada
- Davido, Pasuma àti Yinka Ayefele dábírà lópin ọ̀sẹ̀, aráyé múgbe bọnu
- Oríadé míì nílẹ̀ Yorùbá tún kàgbákò ìkọlù agbébọn
- Ìjà parí! Ẹgbẹ́ dókítà dáwọ́ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ mẹ́wàá dúró
- Duke ti Edinburgh ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 99
Bakan naa ni Pasuma ni orin iwuri ti K1 nkọ lasiko Nikkah ọhun, lo jẹ ki oun fi idunnu oun han, ti omije si bọ loju oun.
Bi o tilẹ jẹpe nkan o lọ daradara laarin K1 ati Pasuma, ọpọlọpọ eniyan lo jẹ iyalẹnu fun lati ri ki K1 wa kọrin nibi Nikkah ọmọ Pasuma.
Bẹẹ si ni inu awọn eniyan dun wi pe awọn mejeeji le gbagbe ọrọ ana, ki wọn si di mọ ara wọn.