Pasuma daughter: Mo bá ọmọ mi yọ̀ bó ṣé di ọmọ ogun orí omi ilẹ̀ Amẹrika - Wasiu Alabi Pasuma

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja olorin fuji, Wasiu Alabi Pasuma ti ba ọmọ rẹ Opeyemi ṣajọyọ lẹyin ti ọmọ naa darapọ ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi ilẹ Amẹrika.

Pasuma sọ pe aṣeyọri ọmọ naa jẹ ohun iwuri fun oun.

Nigba to n kede iroyin naa pẹlu aworan ọmọ ọhun loju opo Instagram rẹ, Pasuma ni "ẹ ba mi ṣajọyọ oriire o, ọmọ mi ti di ọkan lara awọn ọmọ ogun ori omi orilẹ-ede Amẹrika."

O tẹsiwaju pe "O kare ọmọ mi Opeyemi L'Amẹrika fun iwuri nla ti o jẹ fun emi ati iya rẹ, Ọlọrun yoo maa sin ọ lọ ninu irinajo iṣẹ ti o yan laayo yii."

Ti ẹ ko ba gbagbe, obinrin bii mẹta lo bi ọmọ mẹwaa fun Pasuma, ti wọn jẹ obinrin mẹjọ ati ọkunrin meji.

Ọmọ ti Pasuma kọkọ bi ni Wasilat Ajibola to kẹkọọ jade ni fasiti Lead City to wa niluu Ibadan, iyẹn ni ipinlẹ Oyo.

Lara awọn ọmọ miran ti Pasuma tun bi ni Barakat, Wasbar, Amirah, Opeyemi, Sultan, Waris ati Aliyah.

Pasuma jẹ ọkan gboogi lara awọn olorin fuji to milẹ titi julọ ni Naijiria ati kaakiri agbaye.