You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Teni entertainer: Idi ti mi ò kì ń ṣí ìhòhò mi bi àwọn olórin obìnrin míran
- Author, Yemisi Oyedepo
- Role, Broadcast Journalist
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Yoruba bọ wọ́n ni bí fingbáfingbá kò bá fingbá mọ, èyi to tí fin silẹ̀ kò ni parún.
Tení Apata ti gbogbo ènìyàn mọ si Teni Entertainer lo maa n sere ati orin daadaa fun igbadun awọn ololufẹ rẹ sùgbọ́n ǹkan ti ọpọ n sọ nipa Teni ni o bi iroyin yii.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọlólùfẹ́ Teni lórí àtẹjiṣẹ́ twitter lo ti n yin Tẹ́ni pàápàá jùlọ lóri ìmúra rẹ lásikò to ba n ṣe àyẹyẹ orin àti ní gbogbo ìgbà.
- Ìrẹsì ọ̀fadà, ikọ́kọre, àti àwọn oúnjẹ míì tóo lè fí gbádùn ẹ̀mí rẹ lásìkò Kérésì
- Àìbìkítà yíì gbọ́dọ̀ dópin, ìjọba gbọdọ̀ mú ẹ̀dùn ọkàn àwọn aráàlú lọ́kùnkúndùn- Agbẹjọ́rò Àgbà
- Wo àwọn kọ̀ndísàn tuntun tí àwọn olùwọ́de #ENDSARS gbé jáde lẹ́yìn tí wọ́n tú SARS ká
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- Ilé alájà mẹ́ta wó pa èèyan méje, èèyàn 20 farapa ní Obalende, Eko
- A máa ná N10.2 bílíọnù fi tún wáyà iná àti inú ilé Aso Rock ṣe- Buhari
Ọ̀rọ̀ yìí wá di gbigbà bi ẹni gba igbá ọti nígba ti @Benita_Fairy kọ pé Teni fí han pé àwọnn obinrin ọlórin lé ṣe àṣeyori lái ṣí ìhòhò wọ́n sílẹ̀
Ní kété to sọ èyí tan ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ si ni gbàá bi ẹni gba igbá oti, bi àwọn kan ṣe ni kìí ṣe oun nikan ni kìí ṣí ìhòhò rẹ̀ sílẹ̀ ní àwọn míràn ni iṣe ọkunrin lo n ṣe ni kìí ṣe ṣi ara silẹ̀.
Sáàju ni Teni Apata lásìkò to ṣe àbẹ̀wò si ilé iṣẹ́ BBC ti sàlàyé ìdí ti kìí fi ṣi ìhòhò rẹ̀ silẹ̀ nígba gbogbo
Teni sàlàyé pé níní ifẹ́ si ominira ara òun jẹ́ ọkan pàtakì idí ti òun kìí fi ṣi ìhòhò ara òun sílẹ̀.
Ọpọlọpọ lo n sọrọ lori ayelujara pe awokọṣe to yẹ ki awọn ọdọbinrin iwoyi maa wo ni Teni jẹ nitori pe eyi fihan pé ko si nkan ti o ko le da laye ti Olorun ba ti gab funẹ.