You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
2020 budget: Inú mi dùn láti buwọ́lu owó ìṣúná Nàìjíríà l'ọ́jọ́ ìbí mi - Buhari
Aarẹ orileede Naijiria, Muhammadu Buhari ti buwọlu owo isuna ọdun 2020.
Bashir Ahmad to jẹ oluranlọwọ aarẹ lori ọrọ iroyin ayelujara fi fidio bi aarẹ ti ṣe buwọlu owo isuna naa soju opo Twitter rẹ.
Ṣaaju ni Aarẹ Buhari ti kede pe ojuṣe to dun mọ oun ninu ni lati bu ọwọ lu owo iṣuna ọdun 2020 ni ayajọ ọjọ ibi ọdun kẹtadinlọgọrin oun.
Pẹlu igbesẹ yii, orilẹede Naijiria ti pada si lilo eto imurasilẹ ati amulo owo isuna laarin oṣu kini ọdun titi di oṣu kejila ọdun.
Oṣu Kẹwa ọdun 2019 ni aarẹ Buhari fi aba isuna owo naa ranṣẹ si ile aṣofin Naijiria.
Triliọnu mẹwa Naira ni iye owo isuna naa, ti awọn ile aṣofin Naijiria ti ṣaaju fi ọwọ si lẹyin ayẹwo.