Mr President: Mo ti gba pé ológun ni ọkọ mí- Aisha Buhari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lówùrọ̀ òní ní àya àrẹ Muhammadu Buhari, Aisha Buhari kí ọkọ rẹ lori àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ̀, Aarẹ Muhammadu Buhari to n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibí ọdún mẹtàdinlọ́gọ́rin lori oke eepẹ.

Sùgbọ́n ǹkan to yanilẹ̀nu ní pé aya ààrẹ kí ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú orúkọ ti ó ti dá gbọ́mmisi-omí-o-too sílẹ̀ nígboro Naijiria lẹ́nu ọjọ mẹ́ta yìí.

Orukọ yii ni iwe iroyin Punch ní wọn yoo maa fi pe aarẹ Buhari pe ọgagún àgba ní àwọn yóò maa fi si orúkọ Muhammadu Buhari niítori àwọn ǹkan to n wáye lórilẹ̀-ede Naijiria lasiko rẹ.

Aisha Buhari ní "Akú ayẹyẹ ọjọ ibí, ọgágun àgbà ti kò lábàwọ́n"

"Mo gbadúra fún ààbò Allah àti iléra pípé láti tukọ orilẹ̀-èdè Naijiria."

Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọmọ Naijiria ti bẹ̀rẹ̀ si ni dá ìyàwó àarẹ lóhun lóri ikíni rẹ̀ si ọkọ rẹ̀: